Ẹgbẹrun mẹta lawọn araalu yoo maa wọ reluwee lati Eko si Ibadan – Amaechi

Minisita fun ọrọ igboke-gbodo ọkọ nilẹ wa, Rotimi Amaechi, ti kede pe ijọba apapọ ti fọwọ si i pe lati inu oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, ẹgbẹrun mẹta si mẹfa ni awọn to ba nifẹẹ lati wọ ọkọ oju-irin, iyẹn reluwee,  yoo maa san lati ilu Eko lọ si Ibadan.

Lọjọ Ẹti, Furaidee, lo sọ eleyii di mimọ lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ Igbimọ Alaṣẹ agba ileewe ti wọn ti n kọ nipa isakoso igboke-gbodo ọkọ nilẹ wa, (Institute of Transport Administration of Nigeria), niluu Abuja, gẹge bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣe sọ

Minisita to wa fun igboke-gbodo ọkọ yii sọ pe, ‘‘Mo ti gba aṣẹ lati ọdọ Aaarẹ Muhammadu Buhari  lati ṣe ifilọlẹ reluwee ti yoo maa lọ lati Eko si Ibadan ninu oṣu kin-in-ni, ọdun to n bọ, eyi ti yoo mu ki awọn ọmọ  Naijiria ri i bi reluwee to tẹwọn daadaa ṣe n ṣiṣẹ.

‘‘Lonii, mo fọwọ si iye ti awọn ero ọkọ naa yoo maa san lati Eko si Ibadan,  ohun ti a kan ṣe ni pe iye ti a n gbe e lati Abuja si Kaduna naa la oo maa gba lati Eko si Ibadan. Ẹgbẹrun mẹta naira ni awọn ti wọn ba fẹẹ wọ eyi to jẹ ṣe-bo-o-ti-mọ (Ecconomy). Ẹgbẹrun marun-un naira ni awọn to ba fẹẹ jokoo si aaye awọn ọlọla (Business Class), nigba  ti awọn to ba fẹẹ jokoo si aaye awọn onipo kin-in-ni ninu reluwee naa (First Class), yoo jẹ ẹgbẹrun mẹfa naira.

Ọpọ awọn araaalu ti wọn gbọ ikede yii ni wọn n bu ẹnu atẹ lu ijọba lori igbesẹ yii. Wọn ni lati ayebaye, reluwee lo maa n rọju ju ọkọ ilẹ lọ, eyi to maa n mu ọpọ araalu wọ ọ. Ṣugbọn bi reluwee ṣe tun fẹẹ wọn ju mọto lọ bayii fi han bi ijọba yii ṣe fẹran lati maa ni araalu lara.

Ẹgbẹrun kan si meji ni wọn n wọ ọkọ lati ilu Eko si Ibadan bayii gẹgẹ bi onimọto kan ṣe sọ fun akọroyin wa.

3 thoughts on “Ẹgbẹrun mẹta lawọn araalu yoo maa wọ reluwee lati Eko si Ibadan – Amaechi

 1. Alabajo ti won ko fi tete pari ona moto lati Eko si Ibadan
  Eyin nu Oloun na nu

  E ya so fun Agbe toju nkan pe, amodun o jina, ko ma da lasa lati lo hu ebu isu oko re je

  Oju lo n kan boji ijoba ile yi, dan dan ni, oorun n bo nibe.
  Ojo na tun ti di ojo kan loni, ti eni to go a gbon. Lojo na, ologbon a sare kijojijo, ko ni ri eni to ma ran an lowo. Nitori pe, gbogbo awon ti won n pe ni oponu ati alaigbon, ni iye won ti si.

  Omo eranko na o ku gbon tele, sebi ode lo ko omo eranko logbon, ti awon na fi da oju takute mo.
  OJO N BO, O DE TAN.

Leave a Reply