Ẹgbọn Tolulọpẹ ti sọrọ o, o ni iku aburo oun ki i ṣoju lasan

Oriṣiiriṣii awuyewuye lo ti n lọ lori iku to pa ọdọmọbinrin kan, Tolulọpẹ Arotile, ẹni to ku nibi ijamba ọkọ kan to ṣẹlẹ ninu ọgba ileewe ọkọ ofurufu to wa niluu Kaduna ni ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ to kọja, lẹni ọdun mẹrinlelogun. Ọmọbinrin yii ni obinrin akọkọ ni Naijiria ti yoo kọṣẹ mọṣẹ nipa wiwa ọkọ ofurufu agbera-paa ti wọn fi n jagun. Ọrẹ rẹ kan ti wọn jọ lọ sileewe ni wọn sọ pe o ri i, ti o si wa mọto pada sẹyin lati ki i, mọto yii ni wọn lo gba ọmọbinrin ọlọpọlọ pipe yii, to si fori la ogiri, to ṣe bẹẹ ku.

Ṣugbọn ọpọ eeyan lo ti n sọ pe otitọ kan ṣoṣo to wa ninu ọrọ naa ni pe Tolulọpẹ ti ku, ṣugbọn iru iku ti wọn n sọ pe o pa a yii ko mọyan lori, o si nilo iwadii gidigidi. Ẹgbẹ Afẹnifẹre tilẹ sọ ni tiwọn pe niṣe ni wọn pa ọmọ Yoruba naa nitori idi ti ẹnikẹni ko ti i le sọ.

Ẹgbọn rẹ obinrin to wa lọdọ rẹ ki iṣẹlẹ aburu yii too ṣẹlẹ, Damilọla Adegboye, ṣalaye pe adanu nla ni iku aburo oun yii, ibanujẹ ti ko si ṣee fẹnu sọ lo mu ba gbogbo ẹbi. O ni bawo ni pe mọto to n rin pada sẹyin lasan lo kan pa a bẹẹ. Damilọla ni afi ki ileeṣẹ ologun ṣe iwadii ijinlẹ lori iku to pa aburo oun lai tọjọ yii daadaa lati fi da awọn loju pe iku rẹ ko lọwọ ninu rara.

Obinrin naa ni awọn jọ wa nile lọjọ iṣẹlẹ yii ni ti ẹnikan fi pe e lori foonu, pẹlu bo si ṣe sọrọ lọjọ naa, o jọ pe ẹnikan to jẹ ọga fun un lẹnu iṣẹ ni, ṣugbọn ara rẹ lọ tikọ ko fẹẹ lọ, oun loun pinnu pe oun yoo gbe e lọ, ti oun si ṣe bẹẹ. O ni ko ju wakati kan si asiko naa ti oun fi n ka a lori ikanni agbọrọkaye kaakiri pe nnkan buruku ti ṣẹlẹ si i.

Iya to bi Tolulọpẹ ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii akanda ọmọ to ni ibẹru Ọlọrun. O ni aawẹ ati adura jẹ nnkan to fẹran lati maa ṣe.

Leave a Reply