Monisọla Saka
Ọwọ ajọ to n gbogun ti tita, rira ati lilo oogun oloro nilokulo lorilẹ-ede Naijiria, National Drug Law Enforcement Agency (NDLEA), ti tẹ awọn ogbologboo oniṣowo egboogi oloro ti tọkọ-taya kan jẹ olori ẹ.
Awọn tọkọ-taya tọwọ ba lagbegbe Badagry, nipinlẹ Eko yii, ni Ọgbẹni Bọlanle Lookman Dauda ati Arabinrin Ọlayinka Toheebat Dauda.
Nipinlẹ Eko ni ọwọ ti tẹ awọn mejeeji lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ karundinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, pẹlu egboogi oloro kokeeni. Yatọ si egboogi ti wọn ba lọwọ wọn yii, wọn tun tọpasẹ obitibiti ẹru ofin yii dele wọn nipinlẹ Ogun.
Pẹlu ifọwọsowọpọ ileeṣẹ Drug Enforcement Administration, lorilẹ-ede Amẹrika, ni ọwọ NDLEA fi tẹ wọn lagbegbe Ibiye, to wa loju ọna Eko si Badagry, nipinlẹ Eko, lasiko ti wọn fẹẹ gba ẹnubode ori ilẹ gbe ọja naa wọ orileede Ghana.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun yii, ti agbẹnusọ ajọ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, fi atẹjade sita lori ẹ, lo ti ni, “Lasiko ti ilẹ mọ ba wọn, idi mejilelogoji oogun oloro alagbara yii, to gbe iwọn kilo mẹtadinlaaadọta ati aabọ ni wọn ba lara wọn.
“Bakan naa ni awọn oṣiṣẹ NDLEA tun ṣe itọpinpin dele awọn tọkọ-taya yii to wa ni Ojule 24/25, OPIC extension, Ẹpẹtẹdo Road, Agbara, nipinlẹ Ogun. Nibẹ ni wọn ti tun ri idi banba mẹjọ oogun oloro kokeeni yii to gbe iwọn kilo mẹwaa, leyii to mu ki oogun oloro ti wọn gba lọwọ awọn tọkọ-tiyawo naa pe kilo mẹtadinlọgọta ati aabọ (57.5 kg).
Babafẹmi ni awọn afurasi yii ti wa lakata ajọ NDLEA.