Ẹjọ Baba Ijẹṣa: Ẹlẹrii ni ẹẹmeji lọkunrin naa ṣe ‘kinni’ fọmọbinrin ti wọn n sọ

Faith Adebọla, Eko

 Abilekọ Anikẹ Ajayi-Kayọde ti sọ ni kootu ti wọn ti n gbọ ẹjọ gbajugbaja adẹrin poṣonu ilẹ wa, Ọgbẹni Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa pe, iwadii toun fẹsọ ṣe fihan pe eemeji ọtọọtọ ni afurasi ọdaran naa fipa ba ọmọdebinrin ti wọn n sọrọ nipa ẹ lopọ.

Ile-ẹjọ to n gbọ ẹjọ iwa ọdaran abẹle atawọn ẹsun akanṣe, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko ni ọrọ naa ti jade, niwaju Adajọ Oluwatoyin Taiwo.

Ajayi Kayọde ni ẹlẹrii kẹta ti olupẹjọ pe lati fẹri ti ẹsun ifiba bọmọde ṣeṣekuṣe, fifọwọkan ọmọde lọna ti ko yẹ, atawọn ẹsun mẹta mi-in ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa. Ẹlẹrii yii ni ọjafafa oluṣewadii loun, oun si ni alaṣẹ ileeṣẹ ajafẹtọọ awọn ọmọde kan to pe ni Cece Yara Foundation, o lọjafafa loun nidii ṣiṣewadii ẹsun bii eyi, oun si ti bojuto iru iwadii bẹẹ to ju mẹẹdọgbọn lọ.

Ẹlẹrii naa ni iwadii toun ṣe fun ọmọbinrin ti wọn fẹsun kan Baba Ijẹṣa ṣe yankanyankan yii fihan pe ẹẹmeji ọtọọtọ ni iṣẹlẹ ibanilopọ waye laarin wọn, akọkọ ti waye nigba tọmọ naa wa lọmọ ọdun meje, o ni kọkọrọ kan ni afurasi ọdaran naa fi re ọmọ ọlọmọ yii nidii, ninu mọto ayọkẹlẹ kan, ẹẹkeji ni eyi to ṣẹlẹ lọjọ kọkandinlogun oṣu kẹrin ọdun yii nile Damilọla Adekọya ti wọn n pe ni Princess, eyi to di ọran godogbo si Baba Ijẹṣa lọrun yii.

Lẹyin alaye rẹ ni Ẹlẹrii naa ko awọn akọsilẹ abọ iwadii rẹ fun olupẹjọ, iyẹn Alakooso lẹka ileeṣẹ ijọba Eko to n gbeja araalu, Lagos State Directorate of Public Prosecution, Abilekọ Ọlayinka Adeyẹmi, oun naa si taari awọn iwe ati fọran ti wọn fi gba ifọrọwanilẹnuwo ti wọn ṣe fọmọbinrin ọhun silẹ, si Adajọ Taiwo. Wọn sami Ẹsibiiti G, Ẹsibiiti H ati Ẹsibiiti H1 si wọn lara.

Lẹyin atotonu yii, Adajọ sun igbẹjọ to kan si ogunjọ ati ọjọ kọkanlegun, oṣu kẹwaa, o ni ọjọ naa lawọn agbẹjọro olujẹjọ yoo beere ibeere ti wọn yoo si ṣewadii to ba wu wọn lọwọ ẹlẹrii olujẹjọ yii nipa awọn ẹsibiiti rẹ ọhun.

Meji ninu awọn agbẹjọrọ Baba Ijẹṣa ko le yọju si kootu naa, wọn ni wọn ti kọwe ṣaaju lati tọrọ aye nitori ọrọ pajawiri kan to ṣẹlẹ, awọn mejeeji ọhun ni Amofin agba Babatunde Ọgala ati Dada Awoṣika.

Ṣugbọn Baba Ijẹṣa, olujẹjọ, Madam Princess ati ọrẹ rẹ toun naa jẹ ilumọ-ọn-ka onitiata, Iyabọ Ojo, atawọn olulufẹ wọn lọtun-un losi pesẹ si gbọngan ile-ẹjọ naa.

 

Leave a Reply