Ẹjọ Sunday Igboho di ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ ni Kutọnu

Ọjọ Aje, Mọnde, to n bọ yii ni igbẹjọ yoo maa tẹ siwaju, ninu ẹjọ ti ijọba ilẹ Bẹnnẹ fẹẹ ba Oloye Sunday Adeyẹmọ, Igboho, ṣe. Oni lawọn eeyan fọkan si pe wọn yoo tun gbe ọkunrin ajijagbara ọmọ Yoruba naa pada sile ẹjo, ṣugbọn iroyin to jade ṣalaye pe ijokoo tun di ọjọ Mọnde.

Ninu atẹjade kan ti alukoro fun ẹgbẹ Ilana Ọmọ Oodua, Maxwell Adelẹyẹ, gbe jade ni owurọ yii, o ṣalaye pe ki wọn too tun bẹrẹ ẹjọ naa yoo di Monde yii, bo tilẹ jẹ ile-ẹjọ  tabi awọn adajọ ko ṣalaye idi ti wọn fi ṣe bẹẹ ju ti pe ijọba Naijiria ko ti i gbe ẹsun ti wọn fẹẹ tori ẹ da Igboho pada si Naijiria kalẹ, ju awọn ahesọ kan ti wọn ko ti i fi ẹsẹ rẹ mulẹ lọ. Alaroye ti kọkọ gbe e jade tẹlẹ pe awuyewuye kan n lọ labẹlẹ pe awọn adajọ ko ni i jokoo loni-in ni Bẹnnẹ, o si ṣee ṣe ki wọn sun igbẹjọ Igboho siwaju.

Ṣaaju ni Maxwell Adelẹyẹ ti ṣalaye pe lọọya to n ṣoju Igboho ti la a mọlẹ pe ko si bi ijọba Naijiria ṣe le gbe Igboho pada sile ni tipatipa, nitori ko si adehun iru eto bẹẹ laarin Naijiria ati ilẹ Bẹnnẹ: bi Igboho ba da ẹṣẹ kan ni Bẹnnẹ, wọn yoo fi iya rẹ jẹ ẹ nibẹ ni, ki i ṣe ki wọn da a pada, tabi fa a le ijọba Naijiria lọwọ.

 

Leave a Reply