Ekiti, Ogun atawọn ipinlẹ meji mi-in ni kọmiṣanna ọlọpaa tuntun

Oluyinka Soyemi

Awọn kọmiṣanna tuntun ti bẹrẹ iṣẹ nipinlẹ Ekiti, Ogun, Cross River ati Bayelsa lẹsẹkẹsẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nilẹ yii, DCP Frank Mba, lo kede iroyin naa lalẹ yii.

Awọn kọmiṣanna tuntun ọhun ni Mobayọ Babatunde (Ekiti), Edward Awolọwọ Ajogun (Ogun), Abdulkadir Jimoh (Cross River) ati Okoli C. Michael (Bayelsa).

Ṣaaju nileeṣẹ naa ti ṣe agbega fun ẹgbẹrun mẹfa ati mọkanlelẹgbẹta (6, 601) ọlọpaa.

Leave a Reply