Ekiti tun ti padanu ẹni kan sọwọ Korona

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ipinlẹ Ekiti ti padanu ẹnikan sọwọ arun Koronafairọọsi, eyi to sọ iye awọn to ti ku nipasẹ arun naa di marun-un.

Lọsan-an yii ni ijọba Ekiti kede iroyin naa, bẹẹ ni wọn ni awọn mẹrin mi-in ti ko arun naa lẹyin ti esi ayẹwo wọn jade nibudo ayẹwọ Korona to wa l’Ado-Ekiti.

Bakan naa lawọn mẹrindinlogun kan ṣẹṣẹ gba iwosan, wọn si ti pada sile lẹyin ti wọn fidi ẹ mulẹ pe arun ọhun kuro lara wọn.

Ni bayii, eeyan igba-le-mejidinlọgọrin(278) lo ti ko Korona l’Ekiti, ninu eyi ti mẹrinlelaaadọta (54) n gba itọju lọwọ, ti igba-le-mọkandinlogun (219) si ti pada sile

Leave a Reply