Eko lawọn meji yii ti digun gba mọto, ipinlẹ Ogun ni wọn ti mu wọn

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Loruganjọ ogunjọ, oṣu kejila yii, lawọn ọkunrin meji yii, Kenneth Akpa ati Adebayọ Micheal, lọọ digunjale nile kan l’Ahoyaya, nipinlẹ Eko. Mọto ti wọn ji gbe nile naa ni wọn n gbiyanju lati tunṣe lọjọ keji n’Ipẹru, ipinlẹ Ogun, tọwọ awọn ọlọpaa fi ba wọn.

Alaye ti DSP Abimbọla Oyeyẹmi ti i ṣe Alukoro ọlọpaa Ogun ṣe ni pe olobo lo ta awọn ọlọpaa Ipẹru pe mọto Toyota Corolla kan ti wọn ji gbe l’Ekoo ti wa niluu naa, ati pe awọn ọkunrin meji to ji mọto naa gbe n tun un ṣe lọwọ lọdọ mẹkaniiki kan loju ọna Ogere si Ipẹru.

Eyi lo mu ki awọn ọlọpaa lọ si ṣọọbu mẹkaniiki ọhun, nibẹ ni wọn si ti ba Kenneth ati Adebayọ pẹlu mọto naa ti nọmba ẹ jẹ MUS 599 GV, ni wọn ba mu wọn.

Awọn ọlọpaa ranṣẹ si ẹni to ni mọto ọhun, ọkunrin naa ti orukọ ẹ n jẹ James John Ushahemba si ṣalaye pe ni nnkan bii aago kan aabọ oru ọjọ Mọnde lawọn ọkunrin meji ti wọn dihamọra ogun wọle oun l’Ahoyaya, nipinlẹ Eko.

O ni wọn gbe mọto Toyota Corolla oun ti i ṣe 2008 model lọ, wọn gba foonu mẹta lọwọ oun pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgbọn naira (30,000). Tibọn-tibọn lo ni wọn fi gba gbogbo nnkan ọhun lọwọ oun.

Nigba ti iṣẹ ọtẹlẹmuyẹ si ti jẹ kawọn ọlọpaa ri mọto naa gba lọjọ keji ti wọn ji i gbe, CP Lanre Bankọle ti ipinlẹ Ogun ti ni wọn yoo taari awọn afurasi meji yii si ipinlẹ Eko ti wọn ti ṣẹ, ibẹ ni wọn yoo ti gbe wọn lọ sile-ẹjọ.

Leave a Reply