Eko ni Muideen ati Paul ti lọọ jale ni Iniṣa, wọn ti mu awọn ati babalawo wọn

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọṣun ti tẹ Muideen Oṣikọya, ẹni ọdun marundinlogoji, ati Paul Azeez, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn, lori ẹsun ole jija.

Atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fi sita lati Ikorodu, nipinlẹ Eko, ni awọn mejeeji ti wa si ilu Iniṣa.

Nigba ti wọn debẹ, wọn lọ sọdọ Lukman Ọlakunle, ẹni ti wọn pe ni babalawo wọn, to si ti n duro de wọn, iyẹn lo si mu wọn lọ si ṣọọbu kan to wa lagbegbe Oke-Ogun niluu Iniṣa lọjọ kẹtadinlọgbọn oṣu kẹwaa ọdun yii.

Aago kan oru ni wọn lọ sinu ṣọọbu naa, ti wọn si ko ọpọlọpọ kẹẹgi ororo, sẹmofita, tomaati ọlọraa, kọri, spagẹti ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Apapọ owo nnkan ti wọn ji ninu sọọbu naa jẹ ẹgbẹrun lọna ọtalelẹgbẹrin o din mẹwaa (#850,000), inu mọtọ Golf to ni nọmba EKY 762 GP ni wọn ko o si.

Bo ṣe di aago mẹta oru ni wọn fori le ọna Eko, ṣugbọn bi wọn ṣe de ilu Oṣogbo lọwọ tẹ wọn, ti wọn si jẹwọ ibi ti wọn ti n bọ ati ibi ti wọn n lọ.

Lẹyin tọwọ tẹ Muideen ati Paul ni wọn juwe ọdọ Lukman ni Iniṣa, ti awọn mẹtẹẹta si ti n ka boroboro bayii.

Ọpalọla fi kun ọrọ rẹ pe lẹyin iwadii ni awọn mẹtẹẹta yoo foju bale-ẹjọ.

Leave a Reply