Faith Adebọla
Gomina ipinlẹ Kaduna, Mallam Nasir El-Rufai, sọ pe loootọ loun mọ pe awọn gomina ẹlẹgbẹ oun kan ti sọ ileegbimọ aṣofin agba di aga irọgbọku wọn, wọn ti sọ ọ di ile labọ sinmi oko wọn, ti wọn yoo kuro nipo gomina tan, ti wọn yoo gba sẹneeti lọọ sinmi, ṣugbọn ni toun o, oun ko si lara iru awọn gomina bẹẹ, o loun ko le fipo gomina silẹ lọọ maa fẹyin ti gẹgẹ bii sẹnetọ, o ni ko siṣẹ toun fẹẹ lọ ṣe nibẹ ati pe oun o tiẹ ni suuru gbogbo igbokegbodo awọn sẹnetọ yẹn rara, iṣẹ nla lo wa nibẹ fun wọn lati ṣe.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejila, oṣu Disẹmba, ọdun 2022 yii, ni El-Rufai ju ogulutu ọrọ naa nibi eto idanilẹkọọ ọlọdọọdun kan ti wọn maa n ṣe fawọn aṣofin, eyi ti National Institute for Legislative and Democratic Studies (NILDS) l’Abuja, gbe kalẹ.
Gomina naa ni: “Ileegbimọ aṣofin apapọ, ati gbogbo ileegbimọ aṣofin yooku, ṣe pataki gidi ninu eto iṣejọba, bẹẹ ẹka yii ni wọn maa n kọkọ gba danu bii idọti nigbakuugba tawọn ologun ba gbajọba, tawọn ẹka ijọba yooku yoo ṣi maa ba iṣẹ wọn lọ.
Latari eyi, ẹka eto aṣofin ko ri’mu mi, ko si raaye fẹsẹ rinlẹ bii ẹka idajọ ati ileeṣẹ apaṣẹ, tori ẹ ni iru idalẹkọọ bii eyi ṣe ṣe pataki, ka le tubọ ro ẹka aṣofin naa lagbara, ki wọn si le ṣiṣẹ wọn yọri.
“Ọpọ awuyewuye lo wa lori ojuṣe awọn aṣofin, tori ni ọpọ ẹkun idibo gbogbo tawọn aṣofin n ṣoju fun, ireti wọn ni pe teeyan ba ti bọ sipo aṣofin, o gbọdọ maa gbe kọntiraati jade, ko pese iṣẹ fawọn araalu. Wọn lero pe gbogbo onṣejọba lo maa n gbe kọntiraati jade. Wọn o mọ pe awọn aṣofin ko niṣẹ meji ju pe ki wọn ṣofin, ki wọn si mojuto awọn apaṣẹ atawọn adajọ lawọn ibi ti wọn ba ti fẹẹ ki aṣeju bọrọ wọn, lọ.
‘‘Ni temi o, inu mi dun lati wa nibi, ki n le kẹkọọ ni, tori mo mọ daadaa pe iru emi yii o le ba wọn kopa ninu eto iṣẹ aṣofin kankan. Iṣẹ nla lawọn aṣofin n ṣe ki wọn too parọwa, ki wọn le rẹni ṣatilẹyin fun abadofin ti wọn ba gbe kalẹ, kile igbimọ aṣofin naa le fontẹ lu u ko too di ofin, emi o ni suuru iru ẹ ni temi, mi o le ṣe e.
“Iṣe apaṣẹ rọrun, san-an la a rin ni, o si tun ni awọn ẹka ẹka teeyan maa yanṣẹ fun. Gbara tẹnikan ba ti di gomina, iṣẹ ẹ ti rọrun, awọn to maa ṣiṣẹ naa ti wa nilẹ. Ni tawọn aṣofin, aparo kan o ga ju’kan lọ ni gbogbo wọn, ẹgbẹ ara wọn ni gbogbo wọn, ko ṣẹni to lẹnu ọrọ ju ẹnikan lọ, bẹẹ ko sohun to le to keeyan ni lati ṣiṣẹ nibi tẹnu ẹ ko ti tolẹ ọrọ. Iṣẹ abẹnugan awọn aṣofin, tabi ti olori awọn aṣofin apapọ ko fibi kankan wu mi pẹẹ, iṣẹ wọn lo le ju lọ lorileede yii, mi o lẹmi-in ẹ, tori ẹ ni mi o ṣe yọjuran sibẹ. Ko dabi tawa gomina ta a lagbara lati gba-a-yan siṣẹ, ta a si le yọ tọhun danu bii ẹni yọ jiga bo ṣe wu wa.
“Mo mọ pe ọpọ awọn gomina ẹlẹgbẹ mi fẹran lati sọ ileegbimọ aṣofin di ile ifẹyinti wọn ti wọn ba ti kuro nipo gomina, ibẹ ni wọn maa n fẹẹ ritaya (retire) si. Amọ emi o, ki n sootọ ọrọ fun yin, mi o si lara awọn gomina bẹẹ, ko sohun ti mo n wa lọ sile aṣofin, ko siṣẹ mi nibẹ, mi o le wulo nibẹ.”
El-Rufai, kadii ọrọ rẹ pe: “Mo bọwọ fawọn aṣofin o, mo gbedii fun wọn, paapaa awọn ti wọn n ṣiṣẹ takun-takun lati ri i pe ileegbimọ aṣofin wa ko ku. Iṣẹ nla ni wọn n ṣe o.”