Ẹlẹrii tijọba fẹẹ mu wa lẹru n ba oun lati koju Baba Ijẹṣa nile-ẹjọ

Faith Adebọla, Eko

 Meji ninu awọn ẹlẹrii tijọba ipinlẹ Eko fọkan tẹ lati jẹrii ta ko Baba Ijẹṣa lori ẹjọ ifipa ba ọmọde ṣeṣekuṣe to n jẹ lọwọ ti taku lati fara han ni kootu to n gbọ awọn ẹsun akanṣe atorọ to jẹ mọ ifipabanilopọ, eyi to fikalẹ siluu Ikẹja, nipinlẹ Eko. Wọn lẹru n ba awọn, awọn o si le duro niwaju Baba Ijẹṣa jẹrii ta ko o.

Agbẹjọro fun olupẹjọ ti i ṣe ijọba ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Yusuf Sule, lo ṣipaya ọrọ yii niwaju adajọ lọjọ Ẹti, Furaidee yii, nigba to n ṣalaye idi ti awọn ẹlẹrii toun fẹẹ ko wa si kootu ta ko gbajugbaja oṣere tiata ati adẹrin-in poṣonu nni, Ọlanrewaju James Omiyinka, tawọn eeyan mọ si Baba Ijẹṣa, ko fi yọju sile-ẹjọ naa.

Nigba ti Adajọ Oluwatoyin Taiwo to ti n gbọ ẹjọ naa lati ibẹrẹ beere pe ki olujẹjọ ko awọn ẹlẹrii rẹ jade lati sọ ẹri wọn niwaju afurasi ọdaran, iyẹn Baba Ijẹṣa, Ọgbẹni Sule ni:

“Oluwa mi, ọlọpaa ni ẹlẹrii ki-in-ni, ko si le wa si kootu lonii tori wọn ṣẹṣẹ gbe e lọ si ẹka ileeṣẹ ọlọpaa mi-in ni, awọn ọga ẹ ko si ti i yọnda fun un pe ko waa ṣelẹrii ẹjọ yii.

Ẹlẹrii keji loun o le wa si kootu yii lonii, Oluwa mi, o lẹru n ba oun lati duro niwaju olujẹjọ yii koun si maa jẹrii ta ko o.

Gbogbo iṣapa ti mo ṣe lati le ri ọkan ninu wọn mu wa ko mu eso jade. Mo rọ ile-ẹjọ yii lati sun igbẹjọ naa siwaju, mo fi da ile-ẹjọ yii loju pe gbogbo awọn ẹlẹrii wọnyi lo maa ba mi de kootu lọjọ mẹjọ.” Bayii ni agbẹjọro naa tẹwọ ẹbẹ si adajọ.

Adajọ Oluwatoyin Taiwo beere boya olujẹjọ ni ohunkohun lodi si ẹbẹ olupẹjọ rẹ yii, wọn lawọn o ni. Adajọ naa ni oun sun igbẹjọ si ọjọ kọkandinlogun, oṣu kọkanla.

Tẹ o ba gbagbe, ẹjọ to da lori iwa ifipabanilopọ ti wọn fi kan Baba Ijẹṣa loṣu kẹrin, ọdun yii, lo sọ ọkunrin naa dero kootu, atigba naa si ni wa lonii, wa lọla, ti bẹrẹ, bi igbẹjọ ṣe n tẹsiwaju.

Abilekọ Damilọla Adekọya, obinrin alawada kan ti wọn n pe ni Madam Princess, ni akọkọ olufisun Baba Ijẹṣa, o si ti jẹrii ta ko o, bẹẹ lọmọbinrin ọmọọdun mẹrinla tọrọ naa ṣẹlẹ si ti wi tẹnu ẹ.

Leave a Reply