Ẹlẹwọn kan, Amọtẹkun meji pẹlu ṣọja kan ku nibi ikọlu awọn agbebọn si ọgba ẹwọn Ọyọ

Jokẹ Amọri

Ọga agba awọn to n mojuto ọgba ẹwọn nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Noel Ailewon, ti fidi rẹ mulẹ pe ẹlẹwọn kan, ẹṣọ Amọtẹkun kan ati ṣọja kan lo ku nibi ikọlu awọn agbebọn kan to wa si ọgba ẹwọn naa ni ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa, ọdun yii, bo tilẹ jẹ pe awọn amọtẹkun sọ pe meji ninu ọmọ ẹgbẹ awọn lo ku. Nigba to n ba awọn oniroyin sọrọ lọjọ Abamẹta, Satide opin ọsẹ yii, ninu ọgba ẹwọn naa to wa ni Abolongo, niluu Ọyọ, lo sọrọ naa.

O ṣalaye pe lasiko ti ọkan ninu awọn ẹlẹwọn naa fẹẹ fo fẹnsi jade kuro ninu ọgba naa lo ja bọ, to si ku.

O fi kun un pe lasiko ikọlu awọn agbebọn naa ti ẹṣọ Amọtẹkun ati awọn ṣọja koju wọn ni wọn pa Amọtẹkun naa, ti wọn si pa ṣoja kan gẹgẹ bi awọn ṣọja ẹlẹgbẹ wọn to wa nibẹ ṣe fidi rẹ mulẹ.

O ṣalaye pe awọn eeyan naa ko ba ere wa rara, nitori bi wọn ṣe n yinbọn ni wọn n ju bọmbu, ti wọn si ba ọpọlọpọ ile ati dukia ijọba jẹ.

Gbogbo awọn ilẹkun irin to wa ni ẹnu ọna ibi ti awọn ẹlẹwọn yii wa ni wọn fi bọmbu ati ibọn fọ, bẹẹ ni wọn si fi ibọn da ọpọlọpọ awọn ogiri naa lu ti wọn fi raaye wọle.

Nigba tawọn akọroyin n bi Ailewon boya awọn ẹlẹwọn kan to lagbara wa nibẹ ti awọn agbebọn naa tori rẹ wa, ọkunrin yii ni ẹlẹwọn to lagbara kan toun mọ to wa nibẹ ṣi wa ninu ọgba ẹwọn naa, ko sẹni to gbe e lọ. Bo tilẹ jẹ pe o kọ lati darukọ rẹ.

Awọn to le ni ẹgbẹta ninu awọn ẹlẹwọn naa ni wọn ni ọwọ ti tẹ, ti wọn si ti ko wọn pada sinu ọgba ẹwọn naa. Ṣugbọn awọn to din mẹẹẹdọgbọn ni ẹẹdẹgbẹta ni wọn ko ti i ri titi di ba a ṣe n sọ yii.

Ọpọlọpọ awọn ile to wa ninu ọgba naa, to fi mọ ile ori oke ti wọn ti maa n wo gbogbo ohun to ba n lọ ni wọn bajẹ patapata.

Bẹẹ ni wọn fibọn ba mọto awọn ọlọpaa to maa n koju adigunjale ti wọn n pe ni Operation Burst jẹ, ti ẹjẹ si kun inu ọkọ naa.

Ọgba ẹwọn yii kan naa ni Iskilu Wakili, Fulani ti wọn mu fun ẹsun ipaniyan lasiko wahala to ṣẹlẹ niluu Igangan wa. Bakan naa ni ọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Sunday Ṣodipẹ to pa ọpọlọpọ eeyan ni Akinyẹle nigba kan wa ninu ọgba ẹwọn yii kan naa.

Awọn ọga ọgba ẹwọn yii ko le dahun ni pato nigba ti awọn oniroyin beere nipa Wakili ati Sunday boya wọn ṣi wa ninu ọgba ẹwọn naa tabi wọn ko si.

 

 

Leave a Reply