Ẹlẹwọn yii sa kuro l’Edo lasiko iwọde SARS, ipinlẹ Ogun lọwọ ti tẹ ẹ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Ọkan ninu awọn ẹlẹwọn to gba ituṣilẹ ojiji lasiko iwọde SARS lọdun to kọja ni Obehi Ehis Frank Ogbeh. Ipinlẹ Edo lo ti n ṣẹwọn ẹ kawọn ọmọọta too ṣilẹkun ẹwọn kalẹ to fi raaye sa lọ, ṣugbọn ọwọ ti ba a nipinlẹ Ogun bayii, agbegbe Angulis, Agbado, ni wọn ti mu un.

DSP Abimbọla Oyeyẹmi, Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Ogun, ṣalaye pe awọn kan ni wọn ta teṣan ọlọpaa Agbado lolobo pe ọkunrin kan (Ehis) n rin irin to mu ifura dani lagbegbe naa, iṣesi rẹ si jọ tẹni to lẹbọ lẹru.

Eyi lo mu DPO ibẹ, CSP Kẹhinde Kuranga, da awọn ọtẹlẹmuyẹn sita, wọn ri Ehis mu, wọn si fọrọ wa a lẹnu wo, n lo ba jẹwọ pe ẹlẹwọn loun l’Edo, ninu ọgba ẹwọn ti wọn n pe ni’White House.’

O ni nigba ti wọn fagidi ṣilẹkun ẹwọn naa fawọn lasiko iwọde ENDSARS loun di ominira, o ni boun ṣe sa wa sagbegbe Agbado niyẹn, pẹlu igbagbọ pe ọwọ wọn ko le to oun mọ.

Ṣugbọn ni bayii ti ọwọ ofin ti ba a yii, CP Edward Ajogun ti paṣẹ pe ki wọn gbe e lọ sẹka iwadii, nibi ti wọn yoo ti ṣewadii ọdaran to sa naa finni-finni.

Leave a Reply