Emi ati Aregbẹṣọla ko rira o, ṣugbọn awọn eeyan rẹ kan ṣiṣẹ fun mi lasiko ibo – Adeleke

Mosunmọla Saka

Sẹnetọ Ademọla Adeleke to jawe olubori ninu ibo Ọṣun lọjọ Abamẹta, Satide to kọja yii, ti sọ pe awọn eeyan Ọgbẹni Rauf Arẹgbẹṣọla to jẹ gomina tẹlẹ nipinlẹ ọhun, to si tun jẹ Minisita fun eto abẹle lọwọlọwọ bayii, ṣiṣẹ foun ninu ibo ti wọn ṣẹṣẹ pari naa, bo tilẹ jẹ pe oun ati Arẹgbẹ ko rira soju sọrọ lati beere fun atilẹyin rẹ.

Lasiko to n ṣe ifọrọwerọ pẹlu ileeṣẹ tẹlifiṣan Channels ni oludije dupo labẹ ẹgbẹ asia PDP to tun wọle ibo nipinlẹ Ọṣun sọrọ naa.

Adeleke to gbegba oroke ninu ibo latari ikunsinu to n lọ lọwọ ninu ẹgbẹ APC, eyi ti wọn n sọ pe ija to wa laarin Arẹgbẹṣọla ati Oyetọla to jẹ gomina Ọṣun lo fa a  sọ pe, “Mi o ba Arẹgbẹṣọla ṣiṣẹ. Koda, mi o ba a sọrọ, ṣugbọn awọn iṣọmọgbe rẹ ni mo mọ, awọn bii Kọlapọ Alimi to jẹ ọkan ninu awọn agbẹjọro to waa ṣoju Oyetọla lasiko ẹjọ idibo igba naa.

 

 

Nigba naa lọhun-un ti mo ri Alimi nileẹjọ, nitori eeyan kan to laju ti mo jẹ,  ma a lọ sọdọ wọn lọ ki wọn pe ‘ṣe daadaa ni’. Lẹyin-o-rẹyin lo waa bẹ mi pe oun ti n ro o pe ki lo le mu ki Adeleke maa ki oun. Bawọn ṣe n gbiyanju lati doju ẹ bolẹ to, niṣe lo tun n ki oun.

“Ṣugbọn nigba to ya lo sọ fun mi pe ni gbogbo awọn igba ti mo n ki oun yẹn, pe emi o mọ pe majele ni mo n fawọn tọhun yẹn jẹ. Wọn mọ pe emi ni mo wọle ibo, wọn si padi apo pọ da ibo ru ki wọn le doju mi delẹ, tohun ti bẹẹ naa, mo tun ṣi n ki wọn. Ohun ti mo mọ ni pe, ọrọ Oyetọla ati Arẹgbẹ o wọ mọ.

Alimi pada waa ba mi, o loun ti n wo mi tipẹ, oun si fẹ darapọ mọ ẹgbẹ wa, awa naa si faaye gba a. To ba waa jẹ lori ọrọ Arẹgbẹṣọla, ko ṣe tiwa taara bẹẹ o. Ṣugbọn a mọ awọn jankanjankan lẹgbẹ APC ti wọn fi ẹgbẹ wọn silẹ wa sọdọ wa. Ka ni pe mo ti n ba Arẹgbẹ sọrọ lọna kan tabi omi-in ni, mi o ba sọ pe boya nnkan to jẹ ko fun wọn laaye lati ṣatilẹyin fun mi niyẹn.

 

 

“Awọn ti a n sọrọ wọn yii ki i kuku ṣe ọmọde, wọn lẹtọọ lati sọ boya awọn maa darapọ mọ mi abi bẹẹ kọ. Wọn ti nigbagbọ ninu mi pe emi ni mo maa wọle ni wọn ṣe waa ba mi. Ohun temi o kan ṣaa mọ ni boya Arẹgbẹ pa wọn laṣẹ lati ṣe temi abi bẹẹ kọ, nitori emi ati ẹ o ki n sọrọ”.

Lọjọ Aiku, Sannde to lọ yii, lajọ eleto idibo ilẹ wa, INEC, kede pe Adeleke lo wọle ninu ibo gomina ipinlẹ Ọṣun.

Leave a Reply