Emi ati awọn tẹnanti mi ti ṣepade, faaji la fi pari ẹ

Nigba ti mo de ṣọọbu ti mo royin ohun to n ṣẹlẹ nile, ti mo sọ ohun ti Aunti Sikira n ṣe fun Alaaji lọwọlọwọ fun Safu, ti mo ni niṣe lo ma tilẹkun mọ ọn ti ko jẹ ko jade, ẹrin ni Safu n rin. Mo beere mo ni ki lo n pa a lẹrin-in, o ni ki emi maa wo ni temi. Mo ni ki lo de to fi ni ki n maa wo. O ni ọwọ ti Alaaji wa yẹn, koda ki Aunti Sikira ti i mọle ju bẹẹ lọ, ko si kinni kan to maa ri gba nibẹ, nitori ọkọ toun ti oun fi silẹ yẹn ko le ṣe kinni kan fẹni kan laarin ọsẹ kan sibi ta a wa yii. O ni obinrin to ba gbe Alaaji sabẹ lọwọ yii, o kan gbe e sabẹ lasan ni, ko le ri kinni kan gba.

Mo ma kan n wo ẹnu ẹ ni o. Safu ni o da oun loju pe laarin ọsẹ kan, kinni Alaaji ko le ṣiṣẹ gidi kan fẹnikan, o ni ara ẹ ko tiẹ ni i dide ni. Mo ni ṣe oogun lo lo ni abi kin ni! O ni oogun bii ti bawo. Nibi ti oun lo o de ni, nibi ti oun baṣẹ de lara ẹ, o ni nigba toun mu Alaaji, igba to ya, funra ẹ lo bẹ oun, sibẹ oun o fi i silẹ. O ni nigba tawọn tun ji ni fẹẹrẹ toun ni o ya, ẹbẹ buruku lo n bẹ, igba toun naa si fi ọwọ gbe kinni naa jo ti oun ri i pe o ti rọ patapata loun yọnda ẹ, ati pe rirọ to rọ yẹn, ti oun foju ara oun ri i yẹn, ki i ṣe Aunti Sikira ni yoo ji i dide, o kan maa maa fiya jẹ ara ẹ ni.

Iyẹn tiẹ waa fi ọkan mi balẹ diẹ, nitori gbogbo ohun to n ja mi laya naa niyẹn, pe Ọlọrun ma jẹ ki awọn ọmọbinrin wọnyi ṣe ọkọ mi leṣe fun mi. Ṣe ijaya mi naa ko si bọ soju ọna, ẹni kan ṣọṣo lo sun ti i yẹn to ni o da oun loju pe kinni ẹ ko ni i ṣiṣẹ fun odidi ọsẹ kan yii, nitori bi oun ṣe lo o. Eyi to si sọ pe Alaaji n bẹ oun yii naa ba mi lẹru, nitori Alaaji ki i fẹ iru ẹ, ki i fẹ ki obinrin pa oun layo. To ba fi waa di pe o n bẹ ẹni kan bayii, iyẹn ti fẹẹ pa a ni. Oun naa ti ko si mọ iwọn ara ẹ, ẹni to yẹ ko tilẹkun mọri ti Aunti Sikira fi maa wabi gba lọ, o tun jẹ ko wọ oun jade.

Ewo tiẹ ni temi, gbogbo wa naa la kuku jọ ni ọkọ ọhun, ohun to ba wu wọn ki wọn fi i ṣe, oju gbogbo wa ni yoo jọ ja a, ohun toun naa fọwọ fa lo n ri yẹn. Mo si sọ bẹẹ fun Safu, pe ko rọra maa ṣe ọkọ fun mi. Oun naa ni ki n ba ọkọ mi sọrọ pe ko jẹ ki oju rẹ wa nibi kan, o ti niyawo kekere, ko si ohun to tun yẹ ko maa wa kiri lọdọ awọn iya arugbo, bi ko ba si ti gba bẹẹ, to jẹ ọdọ wọn lo fẹẹ maa paara, ko ṣaa ma yọ oun lẹnu, nitori to ba n yọ oun lẹnu, oun yoo maa gbe ija gidi fun un ni. Safu ni bi oun ṣe wa yẹn, bi ko de ọdọ oun loṣu mẹta ko ṣe oun ni nnkan kan, ṣugbọn ohun ti oun ko ni i gba ni ko maa lọọ ṣe e nita, ko foun silẹ. Ni mo ba ni ‘Tọọọ!’

Eyi ti a kuku tiẹ n wi dun, wọn tun ko mi si inawo mi-in lọja. Emi o kuku mọ bi gbogbo wọn ti ṣe gbọ nipa ọrọ ilẹ yii, ṣugbọn wọn ti gbọ, gbogbo adugbo wa yẹn, awọn ṣọọbu to yi mi ka, ati ile kan si meji nibẹ ni wọn ti gbọ pe emi ni mo ra ilẹ ṣọọbu mi. Ohun to si jẹ ki n mọ ko ju ti awọn tẹnanti ibẹ ti wọn waa ya ki mi ni ṣọọbu lọ. Laaarọ kutu. Ko pẹ ti emi ati Safu rojọ ọkọ ẹ tan, bi mo ṣe ri wọn ti wọn tẹle ara wọn ree. Ile ti emi n sọ pe mo mọ iye awọn ti wọn wa nibẹ, aṣe irọ ni, nitori awọn mejila ni wọn wa, wọn si ni aṣoju lasan lawọn jẹ fawọn to ku.

Ko ya ki n maa beere pe ẹyin meloo lẹ wa wa nile ọhun, nigba ti ẹyin agbalagba mejila ba jẹ aṣoju awọn to ku. Ṣugbọn n o beere o, koda mo ṣe daadaa si wọn. Ọkunrin kan ti wọn n pe ni Mukaila Ejo lo ṣaaju wọn wa, boya oun ni olori awọn tẹnanti, nitori mo gbọ nigbẹyin pe ibẹ lo bi gbogbo awọn ọmọ ẹ si, meji si ti lọ sile ọkọ ninu wọn. Wọn ni ninu ile yẹn, iyawo mẹrin lo ti fẹ nibẹ, bo tiẹ jẹ meji lo wa lọdọ ẹ bayii. Yara kan naa lo si gba, ko si kuro nibẹ lati igba yẹn. Iyawo meji wa nibẹ bayii, pẹlu ọmọ mẹfa, iyẹn ni pe awọn mẹjọ ni wọn wa ni yara kan.

Moluẹ ni wọn lo n wa tẹlẹ, igba yẹn lemi ti mo ọn daadaa, mo mọ pe moluẹ lo n wa, nitori o maa n paaki iyẹn siwaju ọdọ wa nigba naa. Ṣugbọn latigba ti moluẹ ti lọ, emi o ri i mọ, wọn ṣẹṣẹ sọ pe Marwa lo n wa bayii ni. O ti dagba, agbalagba ni, bi ẹgbẹ wa lo maa jẹ, iyẹn bi ko ba tiẹ ju iru mi lọ. Nitori ẹ ni mo ṣe yaa ki wọn tọwotọwọ, nitori awọn agbalagba pọ ninu awọn ti wọn wa naa. Awọn obinrin mẹta to wa laarin wọn naa paapaa ti dagba, wọn ki i ṣe ọmọde rara. Gbogbo wọn ni mo ki daadaa. Ni kaluku ba wa ibi kan fidi ha, iduro si lawọn pupọ wa ninu wọn.

Wọn ni awọn waa ri mi ni, pe awọn waa bẹ mi ni. Mo ni ẹbẹ bii bawo, wọn ni awọn ti gbọ pe mo fẹẹ bẹrẹ iṣẹ ile naa kiakia, awọn bẹ mi ki n fun awọn ni oṣu mẹta kawọn fi wa ile tuntun. Emi o sọ bẹẹ o. Ṣugbọn mọ mọ pe Aunti Jẹmila lo sọ fun wọn pe mo ti fẹẹ bẹrẹ iṣẹ ile nibẹ. Bi mo ba si tiẹ fẹẹ bẹrẹ iṣẹ ile, se n ko ni i sọ fun wọn na ki n too bẹrẹ ni. Ọgbọn ni mo fi gbe ọrọ kalẹ, mo ni bi wọn ṣe wa naa daa, pe ko si bi a oo ṣe bẹrẹ ti n ko ni i pe wọn lati ba wọn sọrọ tẹlẹ, ki n le sọ bi ọrọ naa yoo ti jẹ fun wọn. Inu wọn dun si iyẹn.

Mo waa sọ fun wọn pe oṣu mẹta kọ ni n oo fun wọn, oṣu mẹfa ni. Bi ẹni kan ba si ti sanwo silẹ tẹlẹ ti owo ẹ ko ti i pe, n oo da oṣu mẹfa naa pada fun un. Ni gbogbo ile yẹn, ẹni meji pere lowo ẹ ṣẹku. Ẹni kan ku oṣu meji geere, ti ẹni kan ku oṣu kan aabọ. Awọn onigbese lo pọ, ọdun kan sẹyin lawọn mi-in ti sanwo, wọn ni Koro lo fa a. Awọn ti wọn waa ti jẹwo ki Koro too de nkọ. N o wi nnkan kan naa o, mo ṣaa fun kaluku ni oṣu mẹfa, mo si ni n o da oṣu meji pada fawọn ti owo wọn wa nilẹ. Bi wọn ṣe ti ẹnu bọ adura ree, wọn sadura fun mi nikọọkan ti ori emi naa si wu.

Mukaila Ejo lo fọ gbogbo ẹ loju, o ni ki n sọ igba ti mo fẹẹ wẹ ile tuntun naa fawọn, nitori awọn ko le gba ki n ma wẹ ẹ fawọn o. Ni mo ba ni ki wọn ṣaa mu ọjọ to ba ti wu wọn, ni wọn ba ni ọjọ Jimọ lawọn mu. Nigba ti mo si ni ta ni yoo ṣeto ẹ, oun naa ni gbogbo wọn darukọ, wọn ni baba eto awọn niyẹn, ni mo ba ni ko pada waa ri mi. Agbo ni mo fẹẹ ra tẹlẹ fun wọn, oun lo sọ pe ko ju oun ti awọn bii yara mẹrin le jẹ lọ, la ba ni ka ra maaluu. Oun naa lo ni dandan ni ka pe awọn alaafaa. Awọn alaafaa lo kọkọ waa ṣe adura, lẹyin naa ni wọn pa maaluu, ti wọn se irẹsi ati amala, pẹlu ẹba, funra wọn naa ni wọn ṣe e, bi wọn ṣe da faaji silẹ niyẹn o.

Leave a Reply