Emi ki i ṣe ọmọ Maria o, ẹ ma fi mi we Jesu-Tinubu

Monisọla Saka
Oludije dupo aarẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, ti yọ ara rẹ nínú ọrọ ti awọn kan kọ sinu iwe ipolongo ibo ti wọn n pe ni posita ti wọn lẹ kaakiri igboro ni ọsẹ to kọja yii, nibi ti wọn ti ṣapejuwe igbakeji Aarẹ Yẹmi Ọṣinbajo gẹgẹ bii Judasi to dalẹ Jesu Kristi.
Awọn eegun to wa labẹ aṣọ posita ti wọn lẹ kaakiri yii ni wọn ni jijade dupo aarẹ Ọṣinbajo, bii igba to dalẹ ọga ẹ, iyẹn Tinubu, ti wọn fi we Jesu.
Amọ ṣa o, ninu atẹjade awọn ikọ Aṣiwaju Bọla Tinubu to n ri si eto iroyin, wọn ni Aṣiwaju lodi si awọn ti wọn ṣe posita ọhun gẹgẹ bi wọn ṣe n bu ẹnu atẹ lu Jesu lati ba a le da rogbodiyan ọrọ ẹsin silẹ nitori Jagaban.
Wọn ni ” Ete awọn ti wọn lẹ posita ti wọn fọgbọn gbe itan inu Bibeli, nibi ti Judasi ti dalẹ Jesu kalẹ ki i ṣe nnkan mi-in ju lati fa Aṣiwaju sinu ọrọ to le da wahala silẹ, eyi ko si ṣẹyin awọn ọta Jagaban.

“Iwadii ti fi han pe awọn ti wọn ṣe posita buruku ọhun naa ni wọn ṣagbekalẹ ipolongo ibo to n bẹnu atẹ lu Jesu Olugbala. Wọn ṣe eyi lati mu ki awọn eeyan binu si Aṣiwaju ati lati doju Ipolongo ibo rẹ bolẹ.
” Ipolongo ibo yii ti kuna. O han gbangba pe awọn ti wọn ṣe posita yii fẹ lo ọrọ ẹsin lati dabaru erongba Aṣiwaju, ẹni to jẹ pe oun lo koju osunwọn ju fun aarẹ.
” Gbogbo eeyan lo mọ pe iyawo Aṣiwaju Tinubu, iyẹn Senator Olurẹmi Tinubu, ki i ṣe Krisitẹẹni nikan, ṣugbọn ojiṣẹ Ọlọrun ti a pe ni, eyi si mu ki ajọṣepọ to dan mọran wa laarin Aṣiwaju ati ẹsin Krisitẹni, bẹẹ ọrọ yii ki i ṣe aimọ fun pupọ awọn Biṣọọbu, pasitọ ati awọn wolii latọjọ pipẹ.
“Musulumi ododo ni Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ọrọ ati iṣe rẹ si ṣafihan rẹ bii ẹni to ko tolori tẹlẹmu mọra, paapaa ju lọ lori ọrọ ẹsin. O gbagbọ pe ofin ilẹ Naijiria paapaa gboju agan sì iwa ẹlẹyamẹya.’’

Wọn waa rọ awọn eeyan lati ma ṣe gbọ tẹlẹgan ti wọn fẹ maa fi ori Taye ati Kẹhinde gbara wọn, ki wọn si gbaruku ti Aṣiwaju lati depo aarẹ lọdun 2023.

Leave a Reply