Emi ki i ba wọn digunjale, agbodegba lasan ni mo n ṣe fun wọn – Ṣeun

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ 

“Ẹ wo o, Oluwa mi, loootọ lawọn ọrẹ mi n digunjale, mi o ba wọn jale ri ni temi, agbodegba lasan ni mo n ṣe fun wọn.”

Eyi lawọn ọrọ to n jade lẹnu olujẹjọ ẹni ọdun mọkandinlogun kan, Ṣeun Ajiwẹ, lasiko toun ati ọrẹ rẹ, Abednego Azukwo n fara han nile-ẹjọ Majisreeti to wa l’Oke-Ẹda, niluu Akurẹ, lori ẹsun idigunjale ti wọn fi kan wọn.

Awọn mejeeji ni wọn fẹsun kan pe wọn gbimọ pọ, ti wọn si n digun ja awọn eeyan lole lawọn agbegbe kan niluu Akurẹ.

Eyi ti wọn ṣe kẹyin ni ti obinrin kan, Ọlabisi Ọlasusi, ti wọn fi ibọn ja lole foonu olowo nla kan lagbegbe Ọshinlẹ, ni nnkan bii aago mẹsan-an alẹ si mẹfa aṣaalẹ ọjọ keji, oṣu kọkanla, ta a wa yii.

Lẹyin ti wọn ka ẹsun mejeeji ti wọn fi kan Ṣeun ati ọrẹ rẹ si wọn leti tan ni Amofin Fatokun to n gbẹnuṣọ fun ijọba bẹbẹ pe ki ile-ẹjọ paṣẹ fifi awọn mejeeji pamọ si ọgba ẹwọn Olokuta, titi ti imọran yoo fi wa lati ọfiisi ajọ to n gba adajọ nimọran.

Agbẹjọro awọn olujẹjọ, Ọgbẹni Olugbenga bẹbẹ pe ki adajọ fun oun laaye lati fọrọ wa awọn afurasi naa lẹnu wo. O ni idahun wọn ni yoo sọ boya o yẹ ki wọn ko wọn pamọ sọgba ẹwọn gẹgẹ bii ibeere agbefọba tabi ki wọn gba beeli wọn.

Ṣeun ni amofin ọhun kọkọ kọju si, to si beere lọwọ rẹ boya loootọ lo mọ nipa ẹsun idigunjale ti wọn fi kan an.

Ọmọkunrin yii ko ronu lẹẹmeji to fi fun un lesi pe oun ki i ba wọn jale ni toun, o ni iṣẹ oun ni lati maa ba wọn ṣọna lasiko ti wọn ba fẹẹ ṣiṣẹ ibi wọn tabi ti wọn ba n ṣe e lọwọ.

Nigba ti wọn beere ibeere yii kan naa lọwọ Azukwo ti wọn jọ n jẹjọ, oun jẹwọ pe loootọ loun digunjale ni toun.

Lẹyin ijẹwọ awọn mejeeji ni Abilekọ A. A. T. Oyedele gba ẹbẹ agbefọba wọle, o ni oun fọwọ si i kawọn olujẹjọ mejeeji naa ṣi wa lọgba ẹwọn titi di igba mi-in.

Leave a Reply