Abẹwo Ladọja si Ọba Balogun: Emi o ni ikunsinu kankan si Olubadan ilẹ Ibadan tuntun

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ni Osi Olubadan ilẹ Ibadan, to tun jẹ gomina ipinlẹ Ọyọ tẹlẹ, Sẹnetọ Rasheed Adewọlu Ladọja, ti ṣabẹwo si Olubadan ilẹ Ibadan tuntun, Ọba Lekan Balogun, Alli Okunmade Keji. Nibẹ lo ti sọ pe oun ko ni ikunsinu si Olubadan tuntun naa.

O sọrọ yii lasiko to ṣabẹwo si ọba tuntun yii laafin rẹ to wa ni Alarere, niluu Ibadan.

Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin to ti di Ọtun Olubadan tuntun bayii pẹlu bi ọba mi-in ṣe jẹ, ko sọ ohun to waa ba Olubadan sọ.  

Ladọja ni gbogbo awọn ti wọn n gbe e kiri pe oun ni ikunsinu si ọba tuntun naa ko mọ ohun ti wọn n sọ ni, nitori ko si ohun to jọ beẹ laarin awọn.

Baba naa sọ bo ṣe dọbalẹ gbalaja fun ọba tuntun naa lọjọ ti wọn de e lade lọjọ kọkanla, oṣu Kẹta, ti wọn de e lade gẹgẹ bii Olubadan tuntun lati fi han iru ọwọ to ni fun un.

Lara awọn to tun wa nibi ipade yii gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ilẹ wa (NAN), ṣe ṣalaye ni Oloye Owolabi Ọlakunlẹhin, Gbadamọsi Adebimpe ati Ekarun-un Olubadan, Hamidu Ajibade.

Leave a Reply