Emi kọ ni mo lu iyawo mi pa o, aisan lo pa a-Aafaa Qudus

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Baale ile kan, Aafa Mudasir Qudus, lagbegbe Oke-Apomu, niluu Ilọrin, ti sọ pe irọ funfun balau ni iroyin ti awọn eniyan n gbe kiri pe oun lu iyawo oun lalubami titi to fi ku, o ni aisan lo pa obinrin.

Tẹ o ba gbagbe, ninu oṣu Karun-un, ọdun yii, ni iroyin kan gbilẹ pe ṣe ni aafaa yii lu iyawo rẹ Alaaja Iyabọ, ọmọ agboole Jẹjẹ, ni agbegbe Okekere, niluu Ilọrin, lalubami. Lẹyin eyi lo gbe e lọ si ọsibitu, ti awọn dokita ko si ri ẹmi rẹ du ti iyẹn fi pada ku.

Nigba ti Aafa Mudasir n ba ALAROYE sọrọ, o ni irọ to jinna soootọ ni pe oun lu iyawo oun pa, o ni oun nifẹẹ iyawo naa gẹgẹ bii oju ni, to si jẹ pe ibanujẹ ati adanwo nla ni iku obinrin naa jẹ fun oun, titi di akoko toun n sọrọ yii, ibanujẹ naa ko ti i tan lara. O tẹsiwaju pe iyalẹnu gbaa lọrọ naa jẹ bi wọn ṣe sọ pe oun lu u pa ni. O ni ṣe ti oun ba fẹẹ pa a, ṣe oun aa tun gbe e lọ sile iwosan bi? Ọmọ mẹta ti wọn ti dagba daadaa ni obinrin oloogbe naa bii fun un, gbogbo wọn lo n tọ ni ileewe, ti akọbi si ṣẹṣẹ pari ni ileewe giga Fasiti Al-Ikmal  to wa niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara.

Aafaa rọ gbogbo ọmọ Naijiria ki wọn ma ṣe tẹle awọn iroyin to sọ pe oun lu iyawo oun pa, o ni ibanilorukọjẹ lasan ni, ko si ootọ kankan nibẹ. Awọn ọmọ baba naa jẹrii si i pe ki i ṣe aafaa lo pa iya awọn.

Leave a Reply