Emi kọ ni mo ni ibọn ti DSS lawọn ba nile mi, oogun ibilẹ ni mo fi n daabo bo ara mi-Sunday Igboho

 Faith Adebọla

Emi kọ ni mo ni ibọn ti awọn DSS ni awọn ba nile mi, mi o ki i lo ibọn, oogun ibilẹ ni mo fi n daabo bo ara mi, wọn kan fẹẹ fi ṣakoba fun mi ni.’

Oloye Sunday Adeniyi ti gbogbo eeyan mọ si Sunday Igboho lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan to fi sita lori bi awọn ṣọja ati ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ ṣe ya wọ ile rẹ lọjọ kin-in-ni, oṣu keje yii, ti wọn paayan meji, ti wọn si ba ọpọlọpọ dukia rẹ jẹ.

Igboho ni o jẹ ohun to ba ni lọkan jẹ pe awọn eeyan naa pa ẹrọ ayaworan to le ṣafihan ohun gbogbo to n ṣẹlẹ nile oun, ti wọn si gbe e lọ.

Sunday ni ti ki i baa ṣe pe wọn ni nnkan mi-in lọkan ti wọn fẹẹ ṣe, ati pe wọn n wa gbogbo ọna lati mu oun, o ni nibi ti aye laju de yii, o yẹ ki ẹrọ ayaworan wa lara wọn ti yoo ka ohun gbogbo to ṣẹlẹ silẹ lasiko ti wọn n wọnu ile naa ati nigba ti wọn jade.

O fi kun un pe ki lo de to jẹ oru lawọn eeyan naa wa, ti wọn ko wa ni ojumọmọ, ki wọn si wa pẹlu iwe to fun wọn laṣẹ lati yẹ ile oun wo, to jẹ oru ni wọn waa wa.

Ajijagbara yii ni oun ko baayan ja, bẹẹ loun ko fa wahala, ẹnikẹni ko si ku ninu iwọde ti oun n ṣe.

Leave a Reply