Emi kọ ni mo pa iyawo atawọn ọmọ mi o – Oyediran (Fidio)

Ipari oṣu to kọja ni iroyin naa gbalẹ pe nọọsi kan, Solomon Tunde Oyediran, gun iyawo, ọmọ-ọmọ ati ọmọ aburo iyawo rẹ pa sinu ile wọn to wa niluu Inisha, nipinlẹ Ọṣun.

Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ nigba naa, alẹ ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu keje, ọdun yii, ni Tunde, ẹni to ni Plato Abiye Clinic, gun iyawo rẹ pa sinu ile, ṣugbọn idaji ọjọ keji lawọn araadugbo too mọ nnkan to ṣẹlẹ nigba ti nọọsi naa lọ gbatọju oju ọgbẹ to wa lapa ati ikun rẹ.

Iwadii awọn ọlọpaa lẹyin ti wọn mu Oyediran satimọle ti fidi rẹ mulẹ bayii pe ki i ṣe ọkunrin naa lo pa awọn eeyan mẹtẹẹta.

A gbọ pe ọwọ awọn ọlọpaa ti tẹ ọmọdekunrin kan, Lukman Adewale, ọmọ bibi ilu Iree, ṣugbọn to jẹ pe ilu Inisha lo fi ṣebujoko.

Iṣẹ awọn ti wọn maa n tun nnkan eelo ina to ba bajẹ ṣe, electronics repairer, ni Lukman n ṣe, o si ti pẹ to ti maa n ba iyawo nọọsi naa, Sarah Oyediran, ṣiṣẹ ni ṣọọbu ati ninu ile lọjọ pipẹ.

ALAROYE gbọ pe o ti jẹwọ gbogbo nnkan to ṣẹlẹ fun awọn ọlọpaa.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, Yẹmisi Ọpalọla, fidi ọrọ naa mulẹ, o ni otitọ ti fara han, laipẹ si ni wọn yoo ṣafihan Lukman fun awọn oniroyin.

Fidio ifọrọwerọ pẹlu Oyediran:

 

Leave a Reply