Emi ni mo kunju oṣuwọn ju ninu awọn oludije sipo gomina ninu ẹgbẹ APC l’Ekiti-Ọpẹyẹmi Bamidele

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Alaga igbimọ fun eto ofin ati ẹtọ ọmọ eeyan nileegbimo aṣofin agba, Ọnarebu Bamidele Ọpeyẹmi, ti sọ pe o da oun loju ṣaka pe Gomina Kayode Fayẹmi ko ni i gbe ẹnikankan le ori ọmọ ẹgbẹ APC ninu eto idibo gomina to n bọ lọna.

Ọpeyẹmi juwe ara rẹ gẹgẹ bii ẹni to kunju oṣuwọn ju ninu gbogbo oludije ninu eto idibo naa ni ẹgbẹ Onigbaalẹ.

Aṣofin agba yii sọrọ naa lọfiisi ẹgbẹ yii niluu Ado-Ekiti l’Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii, nigba to n ba  awọn ọmọ ẹgbẹ APC      sọrọ lati fi erongba rẹ pe oun fẹẹ dije ninu eto idibo fun ipo gomina to n bọ lọna han.

Ọgọọrọ ọmọ ẹgbẹ lo pade aṣofin naa pẹlu ijo ati igbalẹ lọwọ wọn.

Bakan naa ni ẹgbẹ ọlọkada ati ẹgbẹ onimoto ko gbẹyin, niṣe ni wọn jo pade rẹ loju ọna to lọ si ilu Ilawẹ lati Ado-Ekiti, ti wọn si jo wọ adugbo Ajilosun, nibi to ti ba awọn oloye ẹgbẹ naa ṣepade.

Nigba to n ba awọn ọmọ ẹgbẹ sọrọ, Ọpeyẹmi sọ pe ipa pataki ti oun ti ko nipa itẹsiwaju ile aṣofin agba ko lonka, ni pataki ju lọ, idasilẹ ileewe iṣegun oyinbo (University of Medical Science) ati ẹka ileewe imọ ofin si ilu Iyin-Ekiti, ni ilu oun. O ni eleyii jẹ ami ati ẹri pe oun le ṣe gomina ipinlẹ Ekiti.

Lara aṣeyọri to ni oun ṣe gẹgẹ bii aṣofin agba fun Aarin Gbungbun ipinlẹ Ekiti ni wiwaṣẹ fun ọdọ ti ko din ni ogoji, bẹẹ lo ni oun ṣeto ironilagbara fun ọdọ ti ko din ni igba meji.

Ọpeyẹmi sọ pe oun ti ṣe oun gbogbo lati ri i pe jijade oun ko da rogbodiyan ati ija silẹ ninu ẹgbẹ Onigbaalẹ ti oun ti fẹẹ dije.

O ni inu oun dun gidigidi pe ẹgbẹ naa ko ni i fa ẹni kan lọwọ soke gẹgẹ bii oludije kan ṣoṣo, o ni Gomina Kayode Fayemi ko ni i ṣe bẹẹ.

O ṣeleri pe ti wọn ba gba oun laaye lati dije ninu ẹgbẹ Onigbaalẹ ninu eto idibo naa, oun yoo ṣe ohun gbogbo lati tun ipinlẹ naa sọ bii ẹni sọgba.

Alaga ẹgbẹ APC l’Ekiti, Ọgbẹni Paul Ọmọtọṣọ, to sọrọ lorukọ awọn ọmọ ẹgbẹ yooku juwe aṣofin Ọpeyẹmi gẹgẹ bii ẹni to kunju oṣuwọn ninu ọmọ ẹgbẹ APC Ekiti.

O fi da a loju pe ẹgbẹ naa ko ni i gbe ẹnikankan le ori ẹnikẹni ninu eto idibo abẹle to n bọ lọna.

 

Leave a Reply