Emi o ṣaa laiki ọkunrin pasitọ ta a fẹ ọmọ lọwọ ẹ yii

IYA BIỌLA

Igbeyawo Akin ti a ṣe laipẹ yii, a kuku tun ti fi da nnkan mi-in silẹ. Baba yin ti yari mọ mi lọwọ o, o ni afi ki oun jẹ Baba Adinni ti awọn mọṣalaaṣi Oṣodi kan fẹẹ fi oun jẹ, oun ko duro mọ. Igbeyawo ti a ko ti ẹ ti i sinmi lori ẹ ni o, igbeyawo to jẹ Ọlọrun ni ko jẹ ko tuka lọjọ keji. Emi funra mi ni mo si fẹẹ tu u ka nitori ọkunrin Pasitọ to jẹ Baba Atinukẹ yii, ṣe ẹ mọ pe mo n sọ ọ, eeyan keeyan ni. Ẹni to jẹ gbogbo bi a ṣe n rọkẹkẹ to nibi igbeyawo naa ninu ile ẹ, niṣe lo n leju koko si wa, to roju koko bii ẹni ti wọn so pa. Emi o mọ ohun to n bi i ninu.

Ohun to jẹ ki ara ẹ balẹ diẹ ni nigba ti Dele de. Ọmọ mi! Niṣe lo pa gbogbo wọn lẹnu mọ. Oun o wọ aṣọ ṣọja o, kaftan kekere kan lo wọ, to waa de fila awọn Hausa si i. Ṣugbọn awọn ṣọja mẹrin ni wọn tẹle e ti awọn yẹn n bẹri lọ bẹri bọ. Nigba to ti n bọ lawọn eeyan ti n wo o horohoro, nigba to si dewaju to dọbalẹ tan patapata, ara gbogbo awọn ti wọn wa nibẹ balẹ, wọn mọ pe ki i ṣe pe alejo ni, ọmọ mi ni. Iyẹn lo jẹ ki ara pastọ balẹ diẹ, oun naa mọ pe ti oun ba ṣe mẹẹsi, awọn ọmọ to maa gbe oun wa nitosi. Sibẹ naa, emi o laiki gbogbo bo ṣe n ṣe.

Gẹgẹ bii aṣa Yoruba, emi ati Sẹki lọ si ile wọn pada lọjọ keji lati ki wọn, ka si le dupẹ ana lọwọ wọn. Wọn tiẹ waa gba wa daadaa lọjọ keji yii, nitori ọkunrin yẹn ko leju koko mọ. Koda, o tun bẹ mi ki n ma binu bi oun ṣe ṣe si wa lanaa, pe ara oun ko kan lelẹ ni. O ga lara ẹ! Igba ti a si ti ba wọn jokoo diẹ lo ti ni ọrọ pataki kan to ku to yẹ ki oun sọ lanaa ti oun ko ranti sọ, ki oun kuku yaa sọ ọ bayii ka le mọ bi a ti maa ṣe e. Ni mo ba tun ijokoo ṣe, mo ni o daa ka tete sọ ọ, ki awọn ọmọ wa le maa ba aaye wọn lọ.

Emi tiẹ ro pe o fẹẹ sọ fun mi pe oro ile kan wa ti awọn n ṣe nile awọn ti Tinukẹ gbọdọ ṣe nile ọkọ ni o, ṣugbọn ọkan mi kan tun n sọ fun mi pe pasitọ ni, ki i ṣe ohun to fẹẹ sọ niyẹn. N lemi ba n wo ẹnu ẹ, Sẹki naa si ti tẹti. Ni pasitọ ba ni pẹpẹsi o,nigba wo ni a maa sare lọ si rẹjisiri tabi kootu, ti awọn ọmọ maa lọọ ṣe mareeji ti kootu, mareeji ti olofin. Bo ṣe n sọ bẹẹ yẹn ni gbogbo ohun ti mo mọ ati eyi ti mo ti gbọ ni ọrọ mareeji n sare kọja lori mi. Mareeji! Iyawo alarede! Eewọ ile wa ni o. Mo yaa sọ bẹẹ fun un.

Mo ni eewọ ile wa ni, ati pe ko si ọmọ ile wa kankan to n ṣe mareeji, mo ni baba ẹ ko tiẹ gbọdọ gbọ, o maa binu ni. Lo ba ni ti wọn ba maa binu ki wọn binu, oun ko le fi ọmọ fọkọ lai ṣe mareeji. Ọmọ ti a waa ṣe iyawo ẹ ti o kanri mọnu, ti o n kanra kiri inu ile bii alaaganna, oun lo waa fẹẹ ni ki awa lọọ ṣe mareeji fun. Mo ni ko ṣee ṣe, a ko si ri ọrọ naa yanju ti awa fi dide. Iyawo ẹ ṣaa n sọ pe ka ma binu, nitori oun lo sin wa sọna, ọkunrin alagidi yẹn ko jẹ sin wa, a ti danu bi i. Ki eeyan kan ya afẹsin-balujẹ bii ti ọkunrin yii bayii. Yoo ba emi naa nibẹ.

Mo yaa sọ fun Sẹki pe ọjọ ti a ba ribi ni ibi i wọlẹ, oni naa ni n oo yanju gbogbo ẹ, mo ni ka yaa lọ sile Akin, bo ba ti jẹ bi ọkunrin pasitọ yẹn ti n ronu ni ọmọ ẹ to jẹ iyawo Akin naa n ronu, igbeyawo naa ko ni i pẹ, to ba jẹ a maa fagi le ẹ nibẹrẹ bayii, ka tete fagi le e. Nigba ti Tinukẹ ri emi ati Sẹki, o fẹrẹ le ya were, idunnu ni o! Nitori ohun ta a ṣe lanaa fun wọn yẹn si ni. Niṣe lo fo mọ mi gija, Ọlọrun ni ko ni ko gbe mi ṣubu, afi bii ọmọde ti iya ẹ wa lati ilu okeere, bii pe ki i ṣe emi ati oun la jọ wa nile wọn lanaa yii, eyi ya mi lẹnu.

O ya mi lẹnu nitori mo wo oju ẹ, mo ri i pe ki i ṣe ọmọ kan to bẹ, bẹẹ ni eyi to n ṣe yii ki i ṣe pe o fi n ṣe oju aye, lati inu ọkan ẹ lo ti wa. ‘Iya agba, ẹ waa jokoo; Iya agba, ẹ waa jẹun, Iya agba, ẹ waa mumi!’ Mo kan n wo o bo ti n ko gbogbo ounjẹ kalẹ lai beere pe boya mo fẹẹ jẹ tabi n ko jẹ, to tun n mu oriṣiiriṣii ohun ti wọn ni nile jade. Ọkọ iyawo jokoo gọu sẹgbẹẹ kan nibẹ, o kanri mọ kọmputa, o n ṣe bii ẹni pe oun ko ri mi. Ṣugbọn aajo ọmọ yii ko tiẹ jẹ ki n le wi nnkan kan mọ, ọmọ ti sọ ara ẹ di ọmọ wa ninu ile, ko ri ara ẹ bii iyawo.

Mo kuku tiẹ beere lọwọ ẹ, mo ni ṣe inu ẹ dun lati wa sile wa. O ni ninu gbogbo ohun to ṣẹlẹ yẹn, eyi to dun mọ oun ninu ju ni bi oun ṣe di ‘Ọmọ Iya Biọla’ lati ana lọ. Mo ni ṣe ohun to wa wa niyẹn, o ni oun kan ṣoṣo ti oun wa wa naa niyẹn, koun naa di ọkan ninu awọn ọmọ Iya Biọla, ọwọ oun si ti to o, lo ba yiju si ibi ti Akin wa, lo yinmu, lo ni,  ‘ẹni kan ko le maa halẹ mọ mi mọ pe oun lọmọ Iya Biọla, emi naa ọmọ Iya Biọla ni mi.’ Mo waa ri i pe ọlọgbọn lọmọ naa, koda, o fẹrẹ gbọn ju Akin lọ loju mi. Ohun to si tun jẹ ki i n sọ gbolohun kan le e naa niyẹn.

Mo ni ‘Nigba ti awọn baba rẹ ko waa fẹẹ ka sọ ọ di ọmọ yii nkọ o, ti wọn ni afi ki a lọọ ṣe mareeji ni kootu tabi rẹjisiri. Niṣe ni Akin funra ẹ sare gboju soke nibi to wa, lo n wo wa nibi ti awa duro si. Ṣugbọn ko wi kinni kan. Tinukẹ naa lo sọrọ, o ni, ’emi ti sọ fun wọn ki wọn ma fun ara wọn ni wahala kan, awọn ni wọn n daamu ara wọn. Mi o si nile wọn mọ, mo ti wa nile temi. Ohun ti wọn ba n ṣe nile ọkọ mi ni mo maa ba wọn ṣe. Ohun ti ọkọ mi ba fẹ ni mo maa ṣe. Bo ba ni ka lọọ ṣe mareeji, oun lo ni mi, bi ko si ṣe mareeji, ko si eyi to kan mi, ẹjọ ẹ ni!

Ọrọ ọmọ yii ye mi, o ye Sẹki paapaa debii pe niṣe lo ni ‘ọrọ ti yanju, ati ẹyin ati pasitọ, wahala lẹ ko ara yin si, ikan naa lẹyin mejeeji! Ọmọ ti mọ ohun to fẹẹ ṣe!’ Emi naa mọ pe ọmọ ti mọ ohun to fẹẹ ṣẹ. Mo ni iyẹn ni pe ti ọkọ ẹ ba ni ki ẹ lọọ ṣe mareeji, ti emi ba ni ki ẹ ma lọ, o ko ni i gbọrọ si mi lẹnu niyẹn o!’ Ọmọ yẹn tun ni, ‘rara o, iyẹn yatọ o. Ọmọ Iya Biọla ni mi, ohun ti iya mi ba si fẹ lemi maa ṣe o, koda awọn Bọọda Akin ko le da mi duro!’ N l’Akin ba foju ko o mọlẹ, lọmọ ba rẹrin-in, lo n fi Akin ṣe yẹyẹ.

Bi Tinukẹ ṣe fi ọkan mi balẹ niyẹn, idunnu ni mo si ba dele, ki baba yii too bẹrẹ wahala ọrọ Baba Adinni ti wọn fẹẹ fi i jẹ. O kuku tiẹ ti bẹrẹ si i pe ara ẹ ni orukọ mi-in, ‘Baba Adinni to ja si i!’ Mo ni kin ni wọn n pe bẹẹ, o ni ko le ye mi rara, ko le ye mi. Ki emi ṣaa jẹ ka bẹrẹ ipalẹmọ kiakia!

 

Leave a Reply