Emi o ba Gani Adams ja o, iwa rẹ ni ko ba temi mu -Ọbasanjọ

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Olori orilẹ-ede yii nigba kan, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ṣabẹwo si ọkan ninu awọn agba ẹgbẹ Afẹnifẹrẹ, Oloye Ayọ Adebanjọ, nile ẹ to wa ni Lẹkki Phase 1, l’Ọjọruu ọsẹ yii, ọjọ keji, ọsu kejila, lo ba ba Iba Gani Adams níbẹ, lawọn eeyan ba bẹrẹ si i gbe e kiri pe wọn waa pari ija to wa laarin wọn lọdọ Adebanjọ ni.

Bi ọrọ yii ṣe fẹẹ maa gbilẹ ni Ọbasanjọ sare fi atẹjade sita latọwọ akọwe iroyin rẹ, Ọgbẹni Kẹhinde Akinyẹmi.

Ohun ti Ọbasanjọ sọ ni pe oun ko ba Gani Adams ja, ko si nilo koun ba a pari ija kankan nile Adebanjọ.

Atẹjade naa ka bayii “Mi o nija pẹlu Gani Adams, igbesi aye to ti gbe sẹyin ni ko ba temi mu. Nigba ti mo wa nijọba ati nigba ti mo ti kuro nibẹ, mi o gba ki Gani waa ki mi ri.

‘’Bi ẹnikẹni ba waa ro pe ija wa laarin emi ati Gani ta a si fẹẹ pari ẹ, dajudaju, nile mi ni yoo ti waye niluu Abẹokuta”

Ṣugbọn ọpọ eeyan lo n sọ pe aarin Ọbasanjọ ati Aarẹ Ọna Kakanfo ilẹ Yoruba yii ko gun, wọn ni awọn mejeeji ko fẹran ara wọn.

Leave a Reply