Ọlawale Ajapo, Ibadan
Lori ahesọ ọrọ kan to ni i ṣe pẹlu pe Sunday Igboho nífẹẹ sí láti jẹ adari ìkọ Amọtẹkun, ọkunrin to laya bíi kinniun yìí fesi pe “Emi o fẹ ipo Amọtẹkun kankan. Ohun ti emi n so ni pe ki awọn Fúlàní to n ji awọn ọmọ iya mi (awọn Yorùbá) gbe, to n pa wọn nipakupa, fi ilẹ baba wa silẹ.”
Tẹ o ba gbagbe, ni kete ti Sunday Igboho lọ si ilu Igangan, lagbegbe Ibarapa, nipinlẹ Ọ̀yọ́, lati koju awọn Fulani yii, to si le gbogbo wọn danu, làwọn eeyan kan nílẹ̀ Yoruba ti n pariwo pe ki wọn gba ọkunrin naa sinu ẹṣọ Amọtẹkun, ki wọn si fi i ṣe olori wọn.
Ṣugbọn ọkunrin naa ti sọ pe ki i ṣe lati di adari ẹṣọ Amọtẹkun lo jẹ oun logun bi ko ṣe bi alaafia yoo ṣe jọba kaakiri ilẹ Yoruba, ti gbogbo eeyan yoo si wa ni ifọkanbalẹ lai si ipaya awọn Fulani.