Emi pẹlu rẹ ṣi jọ sọrọ lalẹ ana, iyalẹnu lo jẹ pe o ku laaarọ yii- Ọrẹ Dẹjọ Tunfulu

Ọrẹoluwa, Adedeji
Ọkan ninu awọn ti iku oṣere ilẹ wa to maa n dẹrin-in poṣonu yii, Adetokunbọ Kunle, ti gbogbo eeyan mọ si Dẹjọ Tunfulu, ya lẹnu ju ni ọmọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Ṣẹgun, ẹni to ṣalaye pe oun ba oṣere naa sọrọ lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, ko too di pe o ku laaarọ ọjọ Ẹti.
Ọkunrin naa sọ pe oṣere yii gbe ere rẹ kan fun oun lati ba oun ṣiṣẹ lori rẹ, o ni nigba toun ẹdiiti iṣẹ naa tan, oun fi ranṣẹ si i lalẹ ana ti i ṣe ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kẹta, to ṣẹṣẹ pari yii, awọn si jọ sọrọ lori ohun to fẹ koun ṣe si i, ko si si ami tabi ohunkohun ninu ohun rẹ to fi han pe o rẹ ẹ, tabi pe ohunkohun n ṣe e.
O ni iyalẹnu lo jẹ foun nigba ti oun gbọ laaarọ yii pe aisan kan deede ki i mọlẹ loru, ti wọn si sare gbe e lọ si ileewosan, to si jẹ pe iroyin iku rẹ loun pada gbọ.
Oṣere naa ni ko si ẹnikẹni to ti i le fidi aisan to n ṣe e tabi iru iku to pa a mulẹ.
Ọmọ bibi Ikija, niluu Abẹokuta, ni wọn pe Kunle Adetokunbọ ti gbogbo eeyan mọ si Dẹjọ Tunfulu yii. Ọdun 1969 la gbọ pe wọn bi oṣere yii. Ọdun 1987 ni wọn lo bẹrẹ si i ṣe tiata, to si ti kopa ninu aimọye fiimu. Bẹẹ lo ti ṣe awọn tiẹ naa.
Gbogbo awọn oṣere ni wọn ti n daro iku ọkan ninu wọn yii.

Leave a Reply