Ẹmia ilu Gaya, Alaaji AbdulKadir, jade laye lẹni aadọrun-un ọdun

Faith Adebọla

 Lẹyin ọdun mọkanlelọgbọn lori itẹ, ọba alaye onipo ki-in-ni kan nipinlẹ Kano, Ẹmia ilu Gaya, Alaaji Ibrahim AbdulKadir, ti doloogbe lẹni aadọrun-un ọdun.

Oluranlọwọ pataki lori ẹrọ ayelujara si Gomina ipinlẹ Kano, Mallam Ibrahim, lo kede iṣẹlẹ yii lori ikanni ayelujara ipinlẹ Kano, lowurọ Ọjọruu, Wẹsidee yii.

O ni ilu Gaya ati awọn igberiko rẹ ti Ẹmia naa n ṣakoso le lori jẹ ọkan lara awọn ilu ọlọba nla-nla ti wọn n pe ni ẹmireeti (Emirates) marun-un ti to wa nipinlẹ Kano.

Ọdun 1990 ni Oloogbe AbdulKadir gori itẹ, ọdun naa lo gbọpa aṣẹ, lẹyin to ti fi ọpọ ọdun wa nipo Olori agbegbe Kinchi ati Minjibir. Oṣu karun-un, ọdun 2019, ni ijọba to wa lode yii sọ ọ di ọkan lara awọn ọba alaye onipo ki-in-ni.

Leave a Reply