Emir Kano wọlu Ẹgba, o ṣabẹwo si Gomina Dapọ Abiọdun

Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapọ Abiọdun, gba alejo ọba ipinlẹ Kano, Emir Aminu Ado Bayero, lọfiisi rẹ l’Oke-Mosan, l’Abẹokuta lọjọ Iṣẹgun ọsẹ yii. Ọjọ naa ni gomina ṣeleri pe ibagbepọ alaafia to wa laarin ẹya Yoruba atawọn ẹya mi-in nipinlẹ yii yoo maa tẹsiwaju ni.

Abiọdun ṣalaye pe oun faaye gba ibaṣepọ awọn ẹya mi-in nilẹ yii, nitori iṣẹ ilu ko ṣee da ṣe.

O ni eyi lo fa a to fi jẹ pe ajoji wa ninu ikọ iṣejọba oun, gẹgẹ bo ṣe jẹ pe Alaaji Hadi Sani lati ipinlẹ Sokoto ni olori awọn to n gba gomina nimọran lori ọrọ awọn ẹya ti ki i ṣe Yoruba nipinlẹ Ogun.

Emir Kano yii lọba akọkọ ti Gomina Abiọdun gba lalejo lati ilẹ Hausa, latigba to ti bẹrẹ iṣakoso ipinlẹ yii, o loun mọ riri ẹ, oun ko si ni i fa sẹyin ninu mimu ibaṣepọ daadaa to wa laarin ipinlẹ Ogun atawọn ẹya mi-in gbooro si i.

Ninu ọrọ tirẹ, Emir Ado Bayero ṣapejuwe Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedọtun Arẹmu Gbadebọ, toun naa wa nikalẹ, gẹgẹ bii baba oun. O ni ajọṣepọ ọlọdun gbọọrọ lo wa laarin baba oun ati Alake, eyi naa lo si fa a toun fi wa siluu Ẹgba lati ṣabẹwo si gomina, koun si kọ ninu ọgbọn iṣakoso ilẹ Ẹgba.

Emir Aminu ko ṣai sọrọ lori bi ilẹ Ẹgba ṣe jẹ ibi kan pataki ninu itan Naijiria, nitori nibẹ lawọn eeyan bii Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, Oloogbe MKO Abiọla, Oloogbe Lateef Adegbitẹ atawọn eeyan nla mi-in ti wa.

Alake ilẹ Ẹgba naa sọrọ, Kabiyesi sọ pe ajọsẹpọ to danmọnran lo wa laarin ipinlẹ Kano ati ilẹ Ẹgba, Emir Ado Bayero si gba bẹẹ lo jẹ ko waa ṣabẹwo ti yoo mu iṣọkan tẹsiwaju.

One thought on “Emir Kano wọlu Ẹgba, o ṣabẹwo si Gomina Dapọ Abiọdun

Leave a Reply