Emir Katisina sọ fun Ọṣinbajo: Gbọn-in gbọn-in la wa lẹyin rẹ lati di aarẹ Naijiria

Monisọla Saka

Ẹmia ilu Katsina, Abdulmumin Usman, sọ pe Igbakeji Aarẹ ilẹ wa, Yẹmi Ọṣinbajo, ti ni gbogbo iriri teeyan nilo lati tukọ Naijiria gẹgẹ bii aarẹ.
Ọba alaye naa sọ eyi lasiko to gbalejo Igbakeji Aarẹ naa to ṣabẹwo si i laafin rẹ lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Karun-un, ọdun 2022 yii.
Ọṣinbajo to lọ si ipinlẹ Katsina ni itẹsiwaju abẹwo to n ṣe kaakiri awọn ipinlẹ ṣaaju ibo abẹle lati lọọ ri awọn eekan ninu ẹgbẹ oṣelu APC, ni Ọba Abdulmumin ti gba a ni ọpọlọpọ imọran, to si tun gbadura fun un ki adawọle rẹ le yọri si rere.
Nigba ti ọba alaye naa n sọrọ, o ni, “Mo fẹ ko o gba bẹẹ, gbagbaagba la wa lẹyin rẹ, a oo sa gbogbo agbara wa, eeyan to ti ni iriri yatọ gedegede si eeyan to ṣẹṣẹ fẹẹ bẹrẹ, fun idi eyi, ọna lo wa.
“O nilo awọn nnkan kan, nnkan to o nilo naa ni abẹwo ati ifikunlukun, awa la wa lẹsẹkuku, ko o ri i daju pe o n ri awọn aṣaaju, paapaa ju lọ awọn olori ilu, ko o ba wọn rin.
” Mo wa n gba a laduura pẹlu gbogbo ọkan mi pe wa a ṣe aṣeyọri, gbigbe to o fẹ gbẹru nibi ti ẹni iṣaaju gbe e si yii, Ọlọun Allah aa ran ẹ lọwọ”.

Ọba alaye yii tun ni, Ọṣinbajo gẹgẹ bii pasitọ yoo mọ bi wọn ṣe n ba Ọlọrun sọrọ, ati beeyan ṣe n dari ilu pẹlu ibẹru Ọlọrun.
O tẹsiwaju pe, “Mo mọ pe eeyan jẹẹjẹ ni ẹ, ojiṣẹ Ọlọrun to mọ Ọlọrun, a oo gbadura fun ọ in shaa Allah, ṣugbọn mo fẹ ko o gba bẹẹ ninu ọkan rẹ, iṣẹ to gbọdọ di ṣiṣe ni”.
Ninu ọrọ tiẹ, Ọṣinbajo, ti Gomina Aminu Masari ti ipinlẹ Katsina tẹle lọ saafin ọba alaye yii, dupẹ lọwọ ori-ade naa fun gbigba to gba wọn lalejo, ati bo ṣe ko wọn mọra.
O ni, wiwa toun wa si ipinlẹ ọhun, awọn eekan ninu ẹgbẹ APC loun waa ri, nitori awọn wọnyi naa ni wọn yoo yan ẹni ti ẹgbẹ yoo fa kalẹ ninu eto idibo aarẹ ọdun 2023. Ọṣinbajo sọrọ siwaju si i pe, “Mo ti fa ara mi kalẹ lati dije dupo aarẹ orilẹ-ede Naijiria lọdun 2023, n oo si ṣe aṣeyege lagbara Ọlọrun. Aarẹ wa pataki, Muhammadu Buhari yoo fi ọfiisi silẹ fun ijọba tuntun”.
O ṣalaye pe, pẹlu bi oun ṣe ti sin ilẹ yii labẹ iṣejọba Buhari fun odidi ọdun meje, ati gẹgẹ bi aṣoju Aarẹ nigba mi-in, oun ti tele oriṣiiriṣii awọn iriri toun le fi dari orilẹ-ede nla bii Naijiria jọ.
O jẹ ko di mimọ pe oun ti kọ awọn oniruuru ọgbọn, nitori bo ṣe jẹ pe awọn ohun to n dojukọ orilẹ-ede Naijiria lọwọlọwọ bayii ni ọrọ eto aabo ati eto ọrọ aje ti ko rugọgọ, o loun nigbagbọ pe oun ta a le ṣe ni, oun si wa nipo ti o le mu ki awọn nnkan wọnyi lojutuu, ko si dohun igbagbe.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Adajọ agba ilẹ wa, Tanko Muhammad ti kọwe fipo silẹ

Adewumi Adegoke Adajọ agba ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Onidaajọ Ibrahim Tanko Muhammad, …

Leave a Reply

//thaudray.com/4/4998019
%d bloggers like this: