Emmanuel n rin ni bebe ẹwọn, foonu lo ji l’Ado-Ekiti

*Bẹẹ ni Moses to ji ọkada dero kootu

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ọmọ ọdun mọkandinlogun ni Emmanuel Daniel, ṣugbọn o n rin ni bebe ẹwọn bayii pẹlu bo ṣe dero kootu lori ẹsun ole jija.

Akọsilẹ kootu Majisreeti-agba to wa niluu Ado-Ekiti fi han pe ni nnkan bii aago marun-un irọlẹ ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, ni Emmanuel atawọn kan to ti sa lọ bayii lọọ ji foonu ati owo ni Erinfun Quarters, to wa lọna Poli, niluu kan naa.

lọpaa ni awọn eeyan naa ji foonu Tecno Pouvoir 3 Air towo ẹ to ẹgbẹrun mejilelogoji naira (N42,000) ati ẹgbẹrun mẹwaa naira, eyi to jẹ ti Ajibade Adebukọla.

Lẹyin iṣẹlẹ naa niwadii bẹrẹ, kọwọ too pada tẹ Emmanuel nikan, bẹẹ ni wọn ni dandan ni ko jẹjọ, awọn ẹlẹrii si wa nilẹ ti yoo rojọ ta ko o.

Olujẹjọ sọ fun kootu pe oun ko jẹbi, Amofin Kẹhinde Ogunmọdede si bẹbẹ fun beeli ẹ lọna irọrun, eyi ti Majisreeti-agba Adefunmike Anoma faaye ẹ silẹ pẹlu ẹgbẹrun lọna ogun naira (N20,000) ati oniduuro kan ko too sun igbẹjọ sọjọ kejilelogun, oṣu yii.

Nnkan to ṣẹlẹ si Moses Abel naa ko yatọ, ole ni wọn loun atawọn kan lọọ ja lagbegbe Dalimore, l’Ado-Ekiti, oun nikan lọwọ si tẹ lẹyin iwadii.

Awọn ọlọpaa ni ọjọ kin-in-ni, oṣu kẹfa, ọdun yii, lawọn eeyan naa fọgbọn gba ọkada Bajaj kan towo ẹ to ẹgbẹrun marundinlaaadọwaa (185,000), eyi to jẹ ti Ihiniki Johnson.

Moses naa ni oun ko jẹbi, Amofin Emmanuel Sumonu si rọ kootu lati fun un ni beeli, eyi ti Majisreeti Taiwo Ajibade gba pẹlu ẹgbẹrun lọna ọgọrun-un naira (N100,000) ati oniduuro kan.

Ọjọ kẹtadinlogun, oṣu yii, nigbẹjọ yoo bẹrẹ.

Leave a Reply