Emmanuel to lu oṣiṣẹ LASTMA ti dero ahamọ ọlọpaa

Faith Adebọla, Eko

Ahamọ ọlọpaa ni Ben Emmanuel wa titi di ba a ṣe n sọ yii, latari ẹsun pe o lu oṣiṣẹ ajọ LASTMA kan, Ismaila Lukman, lalubami.

ALAROYE gbọ pe ikorita kan lagbegbe Lẹkki, ni oṣiṣẹ ajọ to n ri si igbokegbodo ọkọ nipinlẹ Eko yii ti n dari ọkọ.

Iṣẹ yii ni Lukman n ṣe lọwọ ti wọn ni Emmanuel fi ke si i lẹgbẹẹ titi pe ko ba oun da mọto duro, o loun fẹẹ sọda titi marosẹ, ẹsẹ lo si fi rin debẹ, ki i ṣe mọto.

Wọn ni Lukman juwe fun un pe ko rin pada sẹyin, ko lọọ gun biriiji ẹlẹsẹ to wa nitosi, tori oun ko le tori tiẹ da awọn ọkọ to n lọ to n bọ duro, nigba tijọba ti ṣe biriiji sibẹ.

Idahun yii ni wọn lo bi Emmanuel ninu, lo ba bẹrẹ si i sọrọ ṣakaṣaka si Lukman, o ni ohun to ṣẹlẹ sawọn ọlọpaa SARS maa to ṣẹlẹ soun naa bi ko ba sọra, bẹẹ ni wọn lo bọ saarin titi naa, to fẹẹ funra ẹ da awọn onimọto duro, pe ko le fẹsẹ rin kọja.

Ṣa, ọrọ yii dija laarin wọn, ni Emmanuel ba sẹ oṣiṣẹ LASTMA naa nigbo, irin kan to wa lara fila rẹ si ṣe Lukman leṣe, lori rẹ ba bẹjẹ. Wọn tun lawọn ọdọ mi-in tun dawọ jọ lu oṣiṣẹ ijọba yii.

Ko pẹ sasiko yii lawọn ọlọpaa patiroolu de ibi iṣẹlẹ naa, bẹẹ lọkọ awọn ṣọja to n kọja kan duro, ni wọn ba fi pampẹ ofin gbe Emmanuel, lẹyin ti wọn ti fiya diẹ jẹ ẹ, wọn si ti i mọ teṣan ọlọpaa to wa ni Ilasan, bo tilẹ jẹ pe awọn meji yooku ti wọn jọ lu Lukman ti fẹsẹ fẹ ẹ.

Ọga agba ajọ yii, Ọlajide Oduyọye, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O lawọn ti fi ohun to ṣẹlẹ yii to Kọmiṣanna feto idajọ, Adajọ Moyọsọrẹ Onigbanjo, leti,  o si ti ni kawọn ọlọpaa tete fi iwe ẹsun Emmanuel ṣọwọ, ki wọn le wọ ọ dele-ẹjọ. O lo yẹ ki awọn fi i jofin, kawọn eeyan bii tiẹ le kọgbọn.

Leave a Reply