Emmanuella, ọmọ ọdun mẹwaa, kọle olowo nla fun iya rẹ

Adefunkẹ Adebiyi,Abẹokuta

Iyalẹnu lo jẹ fun ọpọ eeyan nigba ti wọn deede ri fọto ọdọmọdebinrin alawada nni, Emmanuella Samuel, lori ẹka Instagiraamu rẹ pẹlu ile tuntun daradara kan, ti ọmọ naa si kọ akọle sibẹ pe iya oun loun kọ ọ fun.

Ko sohun to fa ijọloju naa ju pe ọmọde gbaa ni Emmanuella, gbogbo ọjọ ori rẹ ko ti i ju mẹwaa lọ gẹgẹ ba a ṣe gbọ, bẹẹ ni ko ṣiṣẹ mi-in ju awada to n ṣe lori ayelujara naa lọ.

Ṣugbọn lopin ọsẹ ta a lo tan yii, Emmanuella fi han pe loootọ loun kere lọjọ ori, ṣugbọn alubarika ati aranṣe ko kan ọjọ ori ẹni.

Niṣe lọmọ naa kọ akọle kan si isalẹ fọto ile to kọ naa, ohun to kọ sibẹ ree:

‘’Mo kọ eyi fun yin, maami. Fun gbogbo adura, ọrọ iyanju ati atilẹyin tẹ ẹ n fun mi. Maami, mo mọ pe ile kekere lẹ sọ pe ẹ fẹ, oun naa ni mo kọ fun yin yii. Ṣugbọn ẹ foriji mi, nitori mo gbọdọ kọ ile awoṣifila fun yin lọdun to n bọ. Ẹ ma mikan, iyẹn kọ lo maa mu wa wọ ina, iya mi pataki lọdun Keresi. Mo nifẹẹ yin’’

Ẹbun ọdun Keresimesi ni ile ti Emmanuella fun iya ẹ yii gẹgẹ bo ṣe wi, o loun tete fun un silẹ kọdun too de ni.

Eeyan to n tẹle ọmọdebinrin yii lori ẹka Instagiraamu rẹ din diẹ lẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (471,000) bẹẹ lo si tun jẹ aṣoju fun ọpọlọpọ ileeṣẹ ti wọn n lo o fun ipolowo ọja, ti wọn si n sanwo to daa fun un.

 

Leave a Reply