EndSARS: Ọlọpaa ṣafihan awọn afurasi to da wahala silẹ l’Ekiti

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ekiti ti ṣafihan awọn ọmọ kekere meji kan atawọn mẹrin mi-in gẹgẹ bii awọn to dana sun ileeṣẹ ọlọpaa mẹta niluu Ikẹrẹ-Ekiti lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja.

Awọn ọmọdekunrin ti wọn jẹ ọmọ ọdun mejila ati mẹtala ọhun ni wọn ṣafihan pẹlu Alao Emmanuel, Ojuko Tobi, Sunday Salihu ati Koṣedaṣe Ọlamilekan.

Nigba to n ṣafihan wọn lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, sọ pe awọn eeyan ọhun lọwọ tẹ lasiko ti wọn gbimọ-pọ pẹlu awọn mi-in lati dana sun olu-ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Ikẹrẹ ati teṣan meji mi-in lẹyin tawọn janduku sọ iwọde EndSARS di nnkan mi-in.

Abutu ni, ‘’Nigba ti iwọde yẹn bẹrẹ, ko si wahala kankan, afi bo ṣe di Tusidee to kọja tawọn kan ya bo awọn teṣan to wa ni Afaọ Ikẹrẹ, ti wọn si dana sun wọn. Wọn ṣe awọn ọlọpaa kan leṣe, awọn to ku si sa asala fun ẹmi wọn.

‘’Awọn afurasi yii jẹwọ pe loootọ lawọn ṣe e, bẹẹ ni wọn darukọ awọn mi-in ti wọn lọwọ si wahala ọhun.’’

Abutu ṣalaye siwaju pe awọn eeyan ọhun tiẹ ko oriṣiiriṣii nnkan ninu yara ti wọn n ko awọn nnkan si lawọn teṣan ọhun ki wọn too dana sun ibẹ. O ni ọpẹlọpẹ awọn ṣọja atawọn ẹṣọ alaabo mi-in to sare lọ sibẹ, nnkan ko ba bajẹ ju bẹẹ lọ.

O waa ni awọn ti n wa awọn to ku to lọwọ si iṣẹlẹ naa, gbogbo wọn ni yoo si foju bale-ẹjọ lẹyin tiwadii ba pari.

Leave a Reply