Ẹni kan dero ọrun nibi ija awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun n’Ilọrin

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọdọmọkunrin kan ti ko si ẹni to mọ orukọ rẹ ti dero ọrun bayii. Ikorita Ọjà-gbọọrọ, niluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara, ni wọn pa a si lasiko tawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun fija pẹẹta lọjọ Aje, Mọnde, ọṣẹ yii.
Ni nnkan bii aago mẹjọ alẹ ọjọ Aje yii ni awọn olugbe agbegbe Ọjagbọọrọ, deede ri awọn gende-kunrin ti wọn n lọ ti wọn n bọ, ti irinsi wọn si mu ifura lọwọ. Ko oloju too ṣẹ ẹ, ibẹru bojo ti gbilẹ ni agbegbe ọhun nigba ti wọn bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ, ti onikaluku si n sa asa fun ẹmi rẹ.
Ẹni ori yọ o dile ni ọrọ da, ti gbogbo opopona si da paroparo. Ṣugbọn lẹyin ti gbogbo nnkan rọlẹ tan ni wọn ba oku ọmọkunrin ti wọn furasi gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ okunkun naa naa loju popo, ti ko si si ẹni to mọ orukọ rẹ. Awọn agbofinro lo waa palẹ oku ọhun mọ.

Leave a Reply