Ẹni kan dero ọrun nibi ija OPC atawọn Amọtẹkun n’Ikire

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọmọkunrin kan, Omikunle Qouyum, la gbọ pe o ti dero ọrun alakeji, nigba ti ẹnikan fara pa yanna-yanna lasiko ti awọn ọmọ ẹgbẹ OPC atawọn ikọ Amọtẹkun wọya ija niluu Ikire.

Gẹgẹ bi olugbe ilu Ikire kan to pe orukọ ara rẹ ni Agboọla ṣe wi, igun meji awọn janduku ti Ojo ati Ojubintin n dari ni wọn kọkọ ja niluu naa lọjọ Aje, Mọnde.

O ni awọn Amọtẹkun ti wọn ko lọ lati lọọ pẹtu si aawọ naa ni awọn pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ OPC agbegbe ọhun ni wọn wọya ija lagbegbe Ori Eeru nibi ti ibọn ti ba eeyan meji, ninu eyi ti Quoyum ti gbẹmi mi.

Nigba ti awọn oniroyin pe alakooso ẹgbẹ OPC nipinlẹ Ọṣun, Ọtunba Deji Aladeṣawẹ, lori iṣẹlẹ naa, o ni alakooso wọn lẹkun tiṣẹlẹ ọhun ti ṣẹlẹ ni ki a ba sọrọ.

Alakooso OPC lagbegbe Ori Eeru, Sodiq Aderonbi fẹsun kan awọn ikọ Amọtẹkun, o ni awọn ni wọn da wahala naa silẹ, to fi di pe wọn yinbọn mọ oun ati Omikunle Qouyum.

Sodiq sọ siwaju pe ileewosan UNIOSUN Teaching Hospital niluu Oṣogbo ni Quoyum ku si lọjọ Tusidee, nigba ti oun ṣi n gbatọju lọwọ pẹlu ibọn ti wọn yin mọ oun ni itan.

Ṣugbọn alakooso ikọ Amọtẹkun nipinlẹ Ọṣun, Ajagun-fẹyinti Bashir Adewinbi sọ pe irọ to jinna soootọ ni ọrọ awọn OPC. O ni ṣe ni awọn Amọtẹkun lọọ ko awọn ti wọn n mugbo lagbegbe kan niluu Ikire, ti awọn amugbo si ṣekọlu si wọn.

O ni nigba ti awọn ikọ mejeeji dojukọ ara wọn ni ibọn ba eeyan meji. Adewinbi fi kun ọrọ rẹ pe ko ṣee ṣe fun awọn Amọtẹkun lati doju ija kọ awọn ọmọ ẹgbẹ OPC laelae.

Ninu ọrọ tirẹ, Alukooro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe loootọ ni ẹnikan lara awọn ti ibọn ba nibi wahala naa ti jade laye, nigba ti ẹnikeji si fara pa.

Amọ ṣa, Ọpalọla ni alaafia ti pada sinu ilu naa nitori ọpọlọpọ awọn ọlọpaa ni wọn ti wa nibẹ bayii.

Leave a Reply