Ẹni kan fara pa nibi iṣẹlẹ ado-oloro to bu nipinlẹ Ọṣun

Florence Babaṣọla

Ọkunrin kan to ni ṣọọbu nidojukọ ileefowopamọ Wema, niluu Okuku, nijọba ibilẹ Odo-Ọtin, nipinlẹ Ọṣun, fara pa yanna-yanna ninu iṣẹlẹ ijamba ado-oloro kan to deede bu nibẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii.

Ọkunrin naa la gbọ pe o n tun iwaju ṣọọbu rẹ ṣe lasiko ti ado-oloro naa deede bu, ti gbogbo awọn to wa layiika si kọkọ sa lọ ko too di pe wọn pada waa gbe e lọ si ọsibitu nigba ti ariwo lọ silẹ.

Ohun ti a gbọ ni pe o ṣee ṣe ko jẹ pe lara awọn ado-oloro ti awọn adigunjale ti wọn lọọ ṣọṣẹ niluu naa lọsẹ to lọ gbe silẹ lo ṣẹṣẹ wa bu gbamu.

Awọn araalu naa ṣalaye pe ado-oloro lawọn adigunjale ọhun fi fọlẹkun banki Wema ati ile kekere ti wọn gbe ẹrọ ipọwo (ATM) si lọjọ Tọsidee to kọja lọhun-un ti wọn lọ sibẹ.

Eeyan meji lo fara kọta ibọn lọjọ naa, ti wọn si ku loju-ẹsẹ, bẹẹ lawọn adigunjale naa ko obitibiti owo lọ nibẹ.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, to ba ALAROYE sọrọ sọ pe ọkunrin ti ado-oloro bu niwaju ṣọọbu rẹ ọhun ti gbatọju to peye, o si ti kuro nileewosan bayii.

Leave a Reply