Ẹni kan ku, ọpọ eeyan tun fara pa ninu ijamba ọkọ l’Ọba-Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Eeyan kan la gbọ pe o ku, nigba tawọn mi-in fara pa ninu ijamba ọkọ to waye loju ọna marosẹ Ọba si Ikarẹ Akoko, lalẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

ALAROYE fidi rẹ mulẹ nipa iṣẹlẹ ọhun pe awakọ jiipu Range Rover  kan ti ko ti i ni nọmba lo ṣeesi ya kuro lọna tìrẹ, nibi to ti n gbiyanju ati pẹwọ fun awọn koto keekeeke to wa lọna, to si ṣe bẹẹ lọọ kọ lu ọkọ bọọsi elero mẹwaa to n bọ lati Ikarẹ Akoko.

Dẹrẹba bọọsi ọhun, Mukaila Olooru, nikan ni wọn lo ku loju-ẹsẹ, nigba ti pupọ awọn ero to gbe naa si farapa yannayanna.

Ọkan ninu awọn oṣiṣẹ ẹsọ oju popo lagbegbe Ikarẹ Akoko to ba wa sọrọ nipa iṣẹlẹ ọhun ni ere asapajude tí awakọ jiipu Range Rover n sa lasiko to n pẹwọ fawọn koto oju ọna lo mu ko lọọ kọ lu ẹni ẹlẹni to wa lọna tìrẹ.

O ni loju-ẹsẹ ti wọn pe awọn lawọn ti de si ojuko ibi tí ijamba naa ti waye, ti awọn si sare ko awọn to ṣeṣe lọ sile-iwosan ijọba to wa n’Ikarẹ. Mọsuari ọsibitu yii kan naa lo ni awọn gbe oku awakọ bọọsi to ku si titi tawọn ẹbi rẹ yoo fi yọju.

Leave a Reply