Ẹni kan ku, ọpọ fara pa lasiko tawọn oloṣelu kọju ija sira wọn n’Itaji-Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Ọkunrin kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ Social Democratic Party (SDP), ni Itaji-Ekiti, ijọba ibilẹ Ọyẹ, nipinlẹ Ekiti, ti pade iku ojiji, nigba ti eeyan mẹfa miiran to tun jẹ ọmọ ẹgbẹ yii tun fara pa yanna yanna ninu ija oṣelu to waye ni Itaji ati Ọyẹ-Ekiti.
Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn ṣalaye pe awọn janduku oloṣelu kan ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ onimọto (RTEAN) ipinlẹ Ekiti, lo kọ lu wọn lakooko ipolongo wọn ni agbegbe naa.
Awọn janduku naa to wọ aṣọ ti wọn ya aworan oludije ninu ẹgbẹ Onigbaalẹ (APC), si, ni wọn ya bo awọn to n ṣe ipoongo naa, ti wọn si bẹrẹ si i yin ibọn soke.
Asiko yii ni ibọn ba ọkunrin kan to jẹ ọmọ ẹgbẹ SDP, ti awọn ọmọ mi-in naa si fara pa yanna yanna.
Ninu iwe kan ti Oludari ipolongo fun ẹgbẹ Ẹlẹṣin nipinlẹ Ekiti, Ọgbẹni Jackson Adebayọ, fi ṣowọ si awọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, opin ọsẹ yii, niluu Ado-Ekiti, lo ti sọ pe awọn janduku oloṣelu naa ti ọga ẹgbẹ onimọto, Ọgbẹni Rotimi Ọlanbiwọnnu, ti wọn n pe ni Mẹntilo ran ni wọn bẹrẹ si i yinbọn si awọn ọmọ ẹgbẹ Ẹleṣin, nigba ti oludije fun ipo gomina ninu ẹgbẹ naa, Oloye Ṣẹgun Oni, n ba awọn ọmọ ẹgbẹ naa sọrọ lọwọ ni ilu Itaji-Ekiti.
Adebayọ ni mẹta lara awọn ọmọ ẹgbẹ SDP ni ibọn ba, ti wọn si wa ni ẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun, lakooko ti a fi n ko iroyin yii jọ. O fi kun un pe ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto naa ni ọkọ ti wọn gbe wa sibẹ ja ju silẹ, ti ọwọ awọn ọmọ ẹgbẹ Ẹleṣin naa tẹ ẹ, ti wọn si fa a le awọn agbofinro lọwọ.
Nigba ti wọn n fi ọrọ wa ọkan lara awọn tọọgi tọwọ tẹ yii lẹnu wo, o jẹwọ pe ọga ẹgbẹ onimoto RTEAN ti ipinlẹ Ekiti ti gbogbo eyan mọ si Mẹntilo lo ran awọn niṣẹ naa.
Wọn ti ko awọn ti wọn fara pa lọ sileewosan, bakan naa ni wọn ti gbe ẹni kan to ku ninu iṣẹlẹ ọhun lọ si mọṣuari, tawọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iwadii lori ọrọ naa ni pẹrẹu.

Leave a Reply