Ẹni ti yoo dari ibo Ondo ki i ṣe ọrẹ Gomina Akeredolu – INEC

Kazeem Aderohunmu

Ajọ eleto idibo Naijiria, INEC, ti sọ pe oun ko ni i lo ọga agba Yunifasiti Ọbafẹmi Awolọwọ fun ipo oludari ajọ ọhun ninu idibo to maa waye lọjọ Abamẹta, Satide ọla yii, nipinlẹ Ondo.

Agbenusọ fun ajọ naa nipa eto iroyin, Amofin Festus Okoye, sọ pe ohun to jẹ ajọ naa logun ni lati ṣeto ibo to yaranti fawọn eeyan ipinlẹ Ondo, ati pe ko si ohun to kan ajọ yii nipa bi awọn oloṣelu PDP ati APC ṣe n fi oríṣiiríṣii ẹsun kan ara wọn.

INEC ti sọ pe oludari ti yoo ṣakoso ibo ọhun kì í ṣe ọmọ ipinlẹ Ondo, bẹẹ ni ko ni ohunkohun i ṣe pẹlu ileewe Ọbafẹmi Awolọwọ gẹgẹ bi Makinde atawọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP ṣe fibosi bọnu lana-an.

Tẹ o ba gbagbe, ariwo nla lo sọ laarin awọn oloṣeku l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii, nígbà ti iroyin kan jade pe Ọjọgbọn Eyitọpẹ Ogungbenro Ogunbọdẹde, ẹni tí i ṣe Ọga agba fun Yunifasiti Ifẹ ni yoo dari eto ibo l’Ondo.

Wọn ni ọrẹ imulẹ loun ati Rotimi Akeredolu, ati pe ọmọ ilu Ọwọ kan naa lawon mejeeji i ṣe. Fun idi eyi, ko si ki ojooro ma si ninu idibo ti yoo waye nipinlẹ naa, nítorí Rotimi Akeredolu ni Ogunbọdẹde yoo ṣíṣẹ fun.

About admin

Check Also

Pasitọ Chibuzor fun awọn obi Deborah ni ile fulaati mẹrinla atawọn ẹbun mi-in

Monisọla Saka O da bii pe iku Deborah, ọmọbinrin ti awọn awọn kan juko pa, …

Leave a Reply

//zeechumy.com/4/4998019
%d bloggers like this: