Ẹni to ba ṣewọde iranti EndSars l’Ọṣun yoo jiyan rẹ niṣu – Kọmiṣanna ọlọpaa

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Kọmiṣanna ọlọpaa nipinlẹ Ọṣun, Wale Ọlọkọde, ti ṣekilọ fun gbogbo awọn ọdọ tabi ẹlẹgbẹjẹgbẹ ti wọn ba ni i lọkan lati ṣewọde iranti ọdun kan wahala EndSars lati gbagbe nipa erongba bẹẹ.

Ọlọkọde, ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, fi sita laipẹ yii sọ pe awọn ti n hu u gbọ pe awọn kan tun fẹẹ ko ara wọn jọ lati ṣeranti ọdun kan ti wahala naa bẹrẹ.

O ni oun ko ni i laju silẹ ki talubo ko wọ ọ, oun ko ni i faaye gba ohunkohun to tun le da hilahilo kalẹ sọkan awọn araalu, idi niyi to fi kilọ pe ko gbọdọ si ikorajọpọ kankan nibikibi bo ti wu ko kere mọ.

Ọlọkọde sọ siwaju pe gbogbo ipa ati agbara ti ileeṣẹ ọlọpaa ni lawọn yoo lo lati fi imu ẹnikẹni to ba tapa si ikilọ yii, nitori rabaraba ti ọdun to kọja ko ti i kuro nilẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe gbogbo awọn DPO ti wọn wa nijọba ibilẹ kọọkan ni wọn ti gbaradi lati dena iwọde ti ko lẹsẹ nilẹ naa.

O kilọ fawọn obi ati alagbatọ lati ba awọn ọmọ wọn sọrọ nibi ti wọn ti n gbọ, nitori ko si aaye fun ikorajọpọ to le da rukerudo silẹ nipinlẹ Ọṣun mọ.

Oṣu kẹwaa, ọdun to kọja, ni iwọde bẹrẹ kaakiri orileede Naijiria lati fi aidunnu han si iwa iṣekupani to n waye lemọlemọ lati ọwọ awọn ọlọpaa SARS, ọpọlọpọ ẹmi ati dukia lo si ba iṣẹlẹ naa lọ nigba naa.

Lopin rẹ nijọba kede titu SARS ka, bẹẹ ni Aarẹ paṣẹ pe ki awọn gomina gbe igbimọ oluwadii kalẹ nipinlẹ wọn lati gbọ ẹdun ọkan awọn ti wọn ti jiya lọna kan tabi omi-in lọwọ awọn agbofinro lorileede yii.

Leave a Reply