Ẹni to ba fẹ ki oku aja gbo nikan lo le maa reti nnkan tuntun lọdọ Buhari – Ọbasanjọ  

“Ẹ jẹ ki n sọ ootọ pọmbele fun yin, Aarẹ Buhari ti ṣe gbogbo nnkan tagbara ati ọgbọn ẹ mọ. Gbogbo ohun to le ṣe lo ṣe yii, ko si le ṣe ju bẹẹ lọ. Ta a ba ni ko ṣe ju eyi to ti ṣe tabi to n ṣe lọwọ yii lọ, niṣe la n fẹ ki oku ẹṣin ki ere mọlẹ ko maa sa a niyẹn o, oku aja ko si le gbo. Tori naa, ko sidii lati maa reti nnkan tuntun lọwọ Buhari.”

Ṣe wọn ni agba lo to oro i lọ, Oloye Oluṣẹgun Arẹmu Ọbasanjọ, Aarẹ ilẹ wa nigba kan, lo fọ keregbe ọrọ yii mọlẹ bẹẹ lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kẹrinla, oṣu kejila yii, niluu Abuja, nibi apero pataki kan ti ajọ Global Peace Foundation and Vision Africa pe lori ipenija eto aabo to n ba Naijiria finra lasiko yii.

Ọbasanjọ ni ko si ọgbọn tuntun kan teeyan le reti pe kijọba Buhari to wa lode yii tun mu wa lati koju iṣoro aabo to mẹhẹ yii, fifi akoko ṣofo ati ireti ofo lasan ni teeyan ba lọọ fi ojo Buhari gbin’ka.

O tẹsiwaju pe:“Ki waa ni ṣiṣe? A o le kawọ gbera ka maa woran bẹẹ. Mo gbagbọ pe lara nnkan ta a gbọdọ ṣe naa ni iru apero ti a n ṣe yii, a o si gbọdọ jawọ lori ẹ. A gbọdọ maa fori kori, ka bẹrẹ si i gbaradi, bawo la ṣe fẹ kijọba to maa gba iṣẹ lọwọ Buhari ri? Buhari ti ṣe gbogbo ohun tagbara ẹ gbe. Adura mi ni pe k’Ọlọrun da ẹmi ẹ si ko le pari iwọnba perete ti saa rẹ ku yii.

“Ṣugbọn ki la fẹẹ ṣe to maa mu ki ijọba to n bọ daa ju ti Buhari yii lọ? Ojuṣe wa bayii niyẹn, gbogbo wa si lọrọ yii kan pata.”

Oloye Ọbasanjọ ni loju toun, igbesẹ ologun ko le da nikan fopin si ipenija eto aabo to fẹju hẹhẹ kaakiri orileede yii, o ni ọrọ naa ti kọja didana ibọn ya awọn afẹmiṣofo ati janduku agbebọn lasan.

O ni ọgbọn ologun pupọ, ọgbọn arọwa diẹ, lo le mu iyatọ wa.

“Awọn eeyan sọ pe kijọba ṣepinnu akin lo le yanju ọrọ, ṣugbọn ni temi, kijọba gbe igbesẹ akin lo daa ju. Ipinnu nikan ko le da yanju ọrọ yii. Ipinnu ati igbesẹ gbọdọ jọ rin papọ ni. To ba jẹ ka kan ṣaa maa rọ agba lu wọn nikan la n ṣe, igbesẹ ologun niyẹn, ṣugbọn iyẹn nikan o ni i ṣẹgun awọn eeṣin-o-kọ’ku wọnyi, o kan le derọ ẹ ni, o le mu ki wahala yii rọlẹ loootọ, ṣugbọn afi ka tun fi ọgbọn arọwa kun un, ta a ba fẹẹ yanju ẹ patapata. Ka wo nnkan ta a le ṣe lati dari awọn eeyan kuro lọna ifẹmiṣofo ati janduku ni”, gẹgẹ b’Ọbasanjọ ṣe wi.

Leave a Reply