Ẹni to ba gbe ẹri ayederu wa siwaju igbimọ oluwadii Ekiti yoo di ọdaran lẹsẹkẹsẹ

Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti

Igbimọ oluwadii tijọba ipinlẹ Ekiti ṣagbekalẹ lori ọrọ awọn ọlọpaa SARS ati ifiyajẹni lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ti ṣeleri lati ṣiṣẹ takuntakun lori bi awọn to ba gbe ẹsun wa yoo ṣe ri idajọ ododo gba.

Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni igbimọ ti Onidaajọ Cornelius Akintayọ jẹ alaga fun ọhun jokoo fun igba akọkọ lati ṣalaye fawọn eeyan pe igbimọ ti yoo fi ootọ inu ṣiṣẹ ni, ati pe awọn ọlọpaa ti wọn ba jiya lọwọ araalu gan-an le kọ iwe ẹsun.

Akintayọ sọ ọ di mimọ pe gbogbo awọn to ba fẹẹ fẹsun kan ẹnikẹni gbọdọ ni ojulowo akọsilẹ ati ẹri, ẹni to ba si gbe ẹri ayederu wa yoo di ọdaran lẹsẹkẹsẹ.

O ṣeleri pe gbogbo awọn to ba fara han niwaju igbimọ naa ni wọn yoo janfaani iwadii ijinlẹ, idi niyi ti wọn fi gbọdọ fidi nnkan to ṣẹlẹ si wọn mulẹ ki igbimọ naa le ran wọn lọwọ, bẹẹ ni ki wọn fọkan tan awọn ọmọ igbimọ naa lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ.

CP Tunde Mobayọ to jẹ kọmiṣanna ọlọpaa Ekiti sọ pe awọn meji loun ti yọ lẹnu iṣẹ laarin oṣu meji si asiko yii nitori pe wọn jẹbi ẹsun ifiyajẹni. O ni oun ko gba iru iwa bẹẹ laaye, ọlọpaa to ba si fi iya jẹ araalu labẹ akoso oun yoo jiya labẹ ofin to gbe ileeṣẹ naa duro.

O waa ro igbimọ naa lati yọnda awọn ọlọpaa ti wọn ti jiya ẹṣẹ wọn tẹlẹ ki wọn ma baa jiya meji lori ẹṣẹ kan ṣoṣo, bẹẹ lo ṣeleri atilẹyin fun wọn lati ṣaṣeyọri.

Ṣaaju ni Amofin Wale Fapohunda to jẹ kọmiṣanna feto dajọ ti sọ pe ijọba Ekiti gbe igbimọ naa kalẹ lati ṣewadii awọn ẹsun ifiyajẹni lọna tuntun, awọn akọṣẹmọṣẹ lawọn ẹka ti yoo wulo fun iṣẹ iwadii ni wọn si wa nibẹ.

O rọ awọn eeyan lati waa sọ ẹdun ọkan wọn, ki wọn si gbagbọ pe wọn yoo ri idajọ ododo.

Leave a Reply