Ẹni to ba le ri Sunday apaayan to sa nitimọle Ibadan, ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun Naira lawọn ọlọpaa yoo fun un, nọmba yii ni kẹ́ẹ pe

Awọn ọlopaa ipinle Ọyọ ti kede ni ọsan oni yii pe ẹnikẹni to ba le ṣe ọna, tabi to ta awọn agbofinro lolobo, ti wọn fi le ri Sunday Ṣodipẹ to n paayan ni Akinyẹle ni Ibadan mu, ẹẹdẹgbẹta ẹgbẹrun Naira (N500,000) ni ileeṣe ọlọpaa yoo fun tọhun, gẹgẹ bii owo imoore. Ọsan yii ni kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Joe Nwachukwu Enwonwu, ṣe ileri naa funra rẹ nIbadan, ki kalulku le mọ pe ọrọ naa ki i ṣe ṣereṣere.

Ọmọ ọdun mokandinlogun ni Sunday, wọn si ṣẹṣẹ mu un laipẹ yii, ti wọn fi i han gbogbo aye, lọjọ kẹtadinlogun oṣu keje to kọja yii, pe ogbologboo apaayan-jẹun ni. Lati igba naa lo ti wa ni itimọle lọdọ awon ọlọpaa o, afi bo ṣe di ọjọ kọkanla oṣu kẹjọ yii to sa mọ wọn lọwọ. Lati igba naa ni wọn ti n wa a ti wọn ko ri i.

Nidii eyi ni ọga ọlọpa pata ni ipinlẹ naa ṣe paṣẹ bayii, pe ki wọn wa Sunday, ki wọn si mu un, ati pe ẹnikeni to ba ran ọlopaa lọwọ lori eyi, owo gidi ni yoo gba lọwọ awọn. Agbẹnusọ awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, Fadeyi Olugbenga, to fọn ọrọ naa sita sọ pe bi ẹni kan ba ti ko firi ohun kan, ko pe aago awọn ọlọpaa yii : 08035632410, tabi 07066003536, lẹsẹkẹsẹ lawọn yoo d alohun, ti won yo si kan an lara.

Iṣẹ ti bẹrẹ naa ree, gbogbo ẹni to ba roye Sunday ko tete sọ fawọn ọlọpaa o.

About Alaroye

Journalist, Press man and News Researcher of the federal Republic of Nigeria

Check Also

Awọn ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori tiṣa to na ọmọleewe to fi ku l’Ekoo

Faith Adebọla, Eko Afaimọ ni tiṣa ti wọn porukọ rẹ ni Ọgbẹni Stephen yii ko …

One comment

  1. Olorun o fun UN won RI,won o si le mu adehun SE,nitori adehun olopa naijira deru ba eniyan to Fe sofofo

Leave a Reply

//unbeedrillom.com/4/4998019
%d bloggers like this: