Ẹni to ba ni ẹri pe mo gba owo-oṣu gẹgẹ bii gomina fọdun mẹjọ ko mu un jade – Arẹgbẹṣọla

Florence Babaṣọla

 

 

 

Ọgbẹni Rauf Adesọji Arẹgbẹṣọla to jẹ gomina ana nipinlẹ Ọṣun ti pe ẹnikẹni to ba da loju pe oun gba owo-oṣu gẹgẹ bii gomina lodidi ọdun mẹjọ nija lati bọ sita waa sọ faraye.

Nigba ti akọwe iroyin fun Arẹgbẹṣọla, ẹni to ti di minisita fọrọ abẹle lorileede yii bayii, Ṣọla Faṣure, n fesi si iroyin kan to jade laipẹ yii pe ọjọ kan ṣoṣo ni ọkunrin naa gba gbogbo owo oṣu ọdun mẹjọ lẹyin ti eeku ida iṣakoso ipinlẹ Ọṣun bọ sọwọ Oyetọla, lo sọ pe irọ lasan, ofuutufẹẹtẹ ni.

Faṣure ṣalaye pe Arẹgbẹṣọla ko tẹwọ gba owo-oṣu ni gbogbo asiko to fi jẹ gomina l’Ọṣun, idi si ni pe ijọba ti pese ilegbee, eto-aabo, irinkerindo, ounjẹ atawọn nnkan amayedẹrun mi-in fun un nigba naa, ko si si nnkan kan to nilo owo lati ra lapo ara rẹ.

Bakan naa ni gbogbo awọn ọmọ rẹ lo ti dagba nigba naa, ti wọn si ti pari nileewe ti ẹnikọọkan wọn n lọ, ko si nilo owo lati san owo-ileewe mọ. Idi niyẹn to fi yọnda owo-oṣu rẹ funjọba ipinlẹ Ọṣun.

O ni ko si ẹni to le ka iroyin eke naa ti ko ni i mọ pe ṣe ni oniroyin ọhun mọ-ọn-mọ fẹẹ ba orukọ rere ti Ọgbẹni Arẹgbẹṣọla ni jẹ, eleyii to si lodi si ohun to yẹ ki eeyan maa ba lọwọ oniroyin to lẹkọọ.

Faṣure fi kun ọrọ rẹ pe oun ba ẹni to wa ni isakoso owo ijọba (Accountant General) nipinlẹ Ọṣun sọrọ, o si fidi rẹ mulẹ pe ko si akọsilẹ kankan niwaju oun lati fi sọ pe Arẹgbẹṣọla gba owo-oṣu kankan lasiko tabi lẹyin to ṣejọba tan.

O waa rọ gbogbo awọn araalu lati ma ṣe gba iroyin ẹlẹjẹ naa gbọ, ki wọn si ri i gẹgẹ bii iṣẹ-ọwọ awọn abanilorukọ jẹ.

Leave a Reply