Ẹni to ba ni mi o ki i ṣe ọmọ Tinubu ko waa ṣayẹwo ẹjẹ fun mi-Tinubu

Jọkẹ Amọri

Oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ APC, Bọla Ahmed Tinubu, ti sọ pe awọn ileeṣẹ iroyin to fẹ ki oun wa sori telifiṣan waa sọrọ fẹẹ fi oun pawo ni, oun si ni bẹẹ kọ, oun ko ṣe.

Eyi wa lara ibeere to dahun nigba ti awọn ọmọ Naijiria to wa ni London, ni United Kindom, n beere ọrọ lọwọ rẹ ni Chatam House, to ti ba wọn sọrọ lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii.

Tinubu ni irọ ni awọn ti wọn n sọ pe oun ko ni iwe ẹri n pa, nitori oun ti gba ojulowo iwe ẹri oun ni Yunifasiti Chcago ti oun ti jade.

Nigba to n sọrọ nipa ọjọ ori rẹ, ọkunrin to ti ṣe gomina Eko ri yii ni ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 1952, ni wọn kọ sinu iwe ẹri ọjọọbi oun, iyẹn nigba ti oun ko tiẹ ti i mọ boya oun yoo ṣoṣelu, ka ma ti i waa sọ pe oun yoo dupo aarẹ ilẹ Naijiria. O fi kun un pe oun ko ni baba mi-in, Tinubu loun n jẹ, ojulowo ọmọ Tinubu ni oun, ẹnikẹni ti eyi ba si ru loju le waa ṣayẹwo ẹjẹ fun oun.

Tinubu ni, ‘‘Ko si ariyanjiyan tabi ohunkohun to ruju. Akọsilẹ mi ṣi wa digbi ni yunifasiti ti mo lọ ti wọn n sọrọ le lori. Gbogbo awọn akọsilẹ mi lo dara, ko si ohun to ruju nibẹ, ileewe Chicago University ti mo lọ le jẹrii si i paapaa. Ni bayii, mo ti gba ẹda ojulowo iwe-ẹri ti mo fi kawe jade ni yunifasiti yii. Koda, ọkan ninu wọn gan-an ti fẹnu ara rẹ sọ pe niṣe loun fi owo oun ṣofo pẹlu bi oun ṣe n wadii ọrọ kiri nipa iwe-ẹri mi.

‘‘Bakan naa ni ileeṣẹ Deloitte, lo kọ mi lẹkọọ gẹgẹ bii oluṣiro owo, ileeṣẹ Mobil si jẹrii si ijafafa mi nigba ti mo wa nibẹ. Ileeṣẹ aladaani ni mo ti goke agba nidii iṣẹ ti mo yan laayo, ta ni ninu awọn alatako mi to le sọ iru eyi nipa ara wọn.

‘‘Ṣebi ọkan ninu awọn alatako mi wa ti wọn ni ki i ṣe ọmọ Naijiria, mi o sọrọ lori iyẹn.

‘‘Mo mọ pe nnkan ẹgbin ati idọti ni ọrọ oṣelu, mo si mọ pe ẹni ti yoo ba wọnu odo oṣelu gbọdọ mura silẹ fun idọti ti yoo yi i lara.’’ Bẹẹ ni Tinubu wi.

Leave a Reply