Ẹni to ba ta ko awọn gomina Guusu lori fifi maaluu jẹko lẹbọ lẹru ni – Gomina Orthom

Faith Adebọla

 Lori ipinnu wọn pe ko gbọdọ si fifi maaluu jẹko ni gbangba lawọn ipinlẹ wọn mọ, Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Orthom, ti kan saara sawọn gomina ipinlẹ mẹtadinlogun iha Guusu ilẹ wa.

Orthom ni igbesẹ akin to dara gan-an, to bọ sakoko, to si maa yanju iṣoro ni ipinnu naa, ati pe ẹnikẹni to ba ta ko igbesẹ naa, o yẹ ki wọn yẹ onitọhun wo daadaa boya ẹni bẹẹ lẹbọ lẹru ni, tabi kiru onitọhun ni erongba buruku kan to fẹẹ ṣe.

Ninu ọrọ kan to sọ nibi ayẹyẹ ‘Ọsẹ awọn oniroyin ati Ibanisọrọ, eyi to waye niluu Makurdi, l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, o ni awọn ẹlẹgbẹ oun ti gbe igbesẹ to yẹ lati fopin si wahala awọn Fulani darandaran agbebọnrin ti wọn n fẹmi ṣofo kaakiri awọn ipinlẹ ti wọn ba de.

O ṣalaye pe ko sidii fun ẹnikẹni lati wa nipo otoṣi lorileede yii pẹlu oriṣiiriṣii nnkan amuṣọrọ ti Ọlọrun fi jinki ipinlẹ ati agbegbe kọọkan, ti aabo to peye ba wa fun ẹmi ati dukia awọn araalu.

“Awọn ẹlẹgbẹ mi niha Guusu orileede yii ti fẹsẹ le ọna to yẹ ka tọ lati yanju iṣoro aabo to mẹhẹ ni Naijiria. Keeyan ṣi maa fẹran jẹko ni gbangba nibi ti aye laju de yii ko boju mu, tori eeyan ti pọ si i, ọlaju si ti gbooro si i.

“Ẹnikẹni to ba ta ko ipinnu lati fopin si fifi maaluu jẹko ni gbangba tawọn gomina naa fẹnu ko le lori lo yẹ ka fura si, boya onitọhun lẹbọ lẹru, boya o fẹẹ gbe igbesẹ aburu kan nikọkọ ni.” Bẹẹ ni Orthom sọ.

Leave a Reply