Ẹnikan gbe ọmọ tuntun ju sori pẹpẹ ṣọọṣi Kerubu l’Akurẹ, lo ba sa lọ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Oludasilẹ ijọ Kerubu ati Ṣerafu Holy Fountain to wa lagbegbe Oda, niluu Akurẹ, Bisọọbu John Ikoko ti ṣalaye ohun toju rẹ ri lori ọrọ ọmọ tuntun ti wọn ba lori pẹpẹ ṣọọṣi rẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii.

Eyi lawọn alaye ti Bisọọbu Ikoko ṣe f’ALAROYE nigba ta a ṣabẹwo si ile-ijosin naa lati fi okodoro iṣẹlẹ ọhun mulẹ.

‘‘Ba a ṣe gbadura tan ninu ile nitori pe ibi ta a n gbe ko fi bẹẹ jinna si ṣọọṣi nidaaji Ọjọruu, Wẹsidee, ni mo deedee n gbọ igbe ọmọ tuntun, ti mo si ṣakiyesi pe inu lati ile-ijọsin wa lariwo naa ti n wa.

Kiakia ni mo sare dide, ti mo si mori le ọna ibẹ ki n le mọ ohun to n ṣẹlẹ. Ẹru ba mi nigba ti mo ṣilẹkun wọle ti mo si ba ọmọ tuntun ti wọn tẹ sinu aṣọ lori pẹpẹ to n ke kikan kikan. Pẹlu iwoye mi, ikoko ọhun ko ti i ju bii ọmọ ọsẹ kan pere lọ.

O da mi loju pe iya ọmọ ọhun funra rẹ lo waa gbe ọmọ rẹ ju síbẹ nitori o ko awọn nnkan itọju ọmọ tuntun bii aṣọ, oogun oyinbo, fida ti wọn fi n fọmọ lounjẹ si ẹgbẹ ibi to tẹ ẹ si.

A ki i ṣilẹkun ṣọọṣi wa silẹ, emi ni mo fọwọ ara mi tilẹkun pẹlu kọkọrọ ka too lọọ sun, titi ni mo si tun ba ilẹkun wa nigba ti mo debẹ laaarọ ọjọ iṣẹlẹ naa. O ṣee ko jẹ ọkan ninu awọn oju fereṣe ile-ijọsi ni obinrin ọhun gba wọle, to si gbe ọmọ silẹ to sa lọ.

Iyawo mi ni mo ran lọ si teṣan Ala, lati lọọ fi ohun to ṣẹlẹ to wọn leti, ko si pẹ rara tawọn ọlọpaa fi de, ti wọn si gbe ọmọ tuntun naa lọ.

Ohun ta a gbọ ni pe, awọn ọlọpaa ti gbe ọmọ naa fun ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn obinrin nipinlẹ Ondo, lẹyin ti wọn ti kọwọ bọ awọn iwe to yẹ.

Leave a Reply