Ẹni kan ku ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ loju ọna Gbọngan s’Ibadan

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọkunrin kan ti padanu ẹmi rẹ ninu ijamba ọkọ to ṣẹlẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, loju-ọna Gbọngan si Ibadan, ipinlẹ Ọṣun.

Alukoro ileeṣẹ ajọ ẹsọ ojupopo l’Ọṣun, Agnes Ogungbemi, sọ pe nitosi ileepo Forte Oil Filling Station, nitosi biriiji Ṣaṣa, nijamba naa ti ṣẹlẹ.

Ogungbemi salaye pe mọto Toyota Previa alawọ eeru to ni nọmba  APM 222 AA lo deede foju ọna silẹ, to si mori le inu igbo latari ere asapajude to n sa.

O ni loju ẹsẹ lọkunrin kan ku, nigba ti eeyan mẹjọ fara pa pupọ. Mẹrin ninu wọn ni wọn ti ko lọ sileewosan OAUTHC fun itọju, nigba tawọn marun-un n gbatọju lọwọ ni Seventh Day Adventist Hospital, Ileefẹ, tori pe aaye ko si fun wọn ni OAUTHC.

Ogungbemi fi kun ọrọ rẹ pe awọn ẹru ti wọn ri ninu mọto naa ti wa lọdọ ajọ ẹṣọ ojupopo, nigba ti awọn ọlọpaa agbegbe Gbọngan ti wọ mọto naa lọ si agọ wọn.

Leave a Reply