Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Nitori iwọde ti awọn kan n gbero lati ṣe lori ọwọngogo epo bẹntiroolu ati owo Naira, Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ Kwara, CP Paul Odama, ti ṣekilọ fun gbogbo olugbe ipinlẹ naa pe ifẹhonu han tawọn kan n gbero lati ṣe lori ọrọ ọwọngogo epo bẹntiroolu ati owo Naira tuntun to n lọ lọwọ lawọn ipinlẹ kan ko gbọdọ waye ni Kwara.
Ninu atẹjade kan ti Alukoro ọlọpaa ipinlẹ ọhun, Ọkasanmi Ajayi, fi sita to tẹ ALAROYE lọwọ niluu Ilọrin, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọṣẹ yii, lo ti lo asiko yii lati kilọ fun gbogbo awọn olugbe ipinlẹ naa, pe ọlọpaa ko ni i faaye gba iwọde ti awọn kan gbero lasiko yii, nitori o ṣee ṣe kawọn janduku kan ja iwọde ti wọn n gbero rẹ ọhun gba mọ wọn lọwọ lati fi da rogbodiyan silẹ ki ohun gbogbo si di idarudapọ.
Kọmisanna gba awọn adari oloṣelu nimọran ki wọn kilọ fun awọn alatilẹyin wọn ki wọn jinna si iwa janduku, ki wọn yee pọnmi oke ru todo. O fi kun un pe ileeṣẹ ọlọpaa yoo maa yide kiri, ti wọn aa si hu gbogbo awọn kọlọransi jade nibikibi ti wọn ba farapamọ si, o jẹjẹẹ lati pese aabo to peye fun gbogbo tibu-toro ipinlẹ Kwara.