Ẹnikẹni to ba n sọrọ to le mu ki awọn eeyan binu si Buhari yoo ri pipọn oju ijọba -Garba

Faith Adebọla

Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, ti fi aidunnu rẹ han si oko ọrọ ti Gomina Samuel Ortom tipinlẹ Benue sọ si i laarin ọsẹ yii latari bi wahala eto aabo to mẹhẹ ṣe n peleke si i nipinlẹ ọhun ati lorileede Naijiria lapaapọ.

Oludamọran pataki fun Aarẹ lori eto iroyin ati ikede, Mallam Garba Shehu, sọ ninu atẹjade kan to fi lede lọjọ Ẹti, Furaidee yii, lori ọrọ ọhun, o ni ọrọ ti gomina sọ nipa Buhari dun Aarẹ gidigidi, ko si daa kawọn to wa nipo aṣaaju ninu eto iṣelu maa sọrọ to le fa iyapa lorileede yii.

O ni apero lọrọ eto aabo to mẹhẹ yii nilo, paapaa latari bi wọn ṣe n fẹmi ṣofo lawọn apa ibi kan lorileede yii, o lo yẹ ka ṣepade lori ẹ ni.

Atẹjade naa sọ pe “Ko sibi tawọn iṣẹlẹ ibanujẹ ti ṣẹlẹ ti aarẹ ki i sọrọ nipa ẹ tabi ko fi aidunnu rẹ han, bẹẹ lo si maa n ba awọn mọlẹbi tọrọ naa kan kẹdun. Aarẹ ti ṣedaro lori awọn eeyan ti wọn da ẹmi wọn legbodo nibudo awọn ogun-le-n-de.

Lafikun, Aarẹ sọ pe bi awọn iṣẹlẹ ipaniyan ṣe n fojoojumọ pọ si i, ti iwa janduku si n peleke si i kaakiri orileede yii, niṣe lo yẹ ka sọ asọye-pọ pẹlu awọn eleto aabo gbogbo, ka si jọ fọwọ sowọ pọ.

“Aarẹ koro oju, o si ya a lẹnu lati gbọ ọrọ ti Samuel Ortom, Gomina ipinlẹ Benue sọ pẹlu ọgọọrọ ẹsun to fi kan Aarẹ funra ẹ ati ijọba rẹ latari awọn iṣẹlẹ ibanujẹ to ṣẹlẹ ọhun.

“Ko sijọba gidi kan tinu ẹ maa dun si bi wọn ṣe n pa awọn agbofinro, awọn ṣọja ati araalu ti ko mọwọ mẹsẹ, paapaa awọn ti wọn ko sibudo IDP.

“Ko yẹ ka maa ti ọrọ oṣelu bọ iṣoro eto aabo ta a n koju yii, ko si yẹ ka maa fọrọ powe fun Aarẹ lọna to le da awuyewuye ati ibinu silẹ.

“Ẹnikẹni ti ajere ba ṣi mọ lori pe o n fọrọ dana ijangbọn silẹ, tabi o n sọrọ to le ru awọn eeyan soke lodi si Aarẹ maa ri pipọn oju ijọba ni, tori Buhari ti jẹjẹẹ pe oun maa pese aabo to peye faraalu ati dukia wọn.” Bẹẹ ni atẹjade naa sọ.

Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Iṣẹgun Tusidee to kọja yii ni gomina Benue bẹnu atẹ lu Aarẹ Buhari lori ọrọ aabo yii, o si fẹsun kan aarẹ pe niṣe lo fọwọ dẹngbẹrẹ mu ipakupa to n waye, ati pe afaimọ ni ki i ṣe pe aarẹ fẹẹ sọ Naijiria di tawọn Fulani nikan tori iṣarasihuwa rẹ lasiko yii jọ bẹẹ.

Leave a Reply